Tag Archives: Lt. Col. Adekunle Fajuyi

Ìránti Aadọta Ọdún ti Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fi ara rẹ ji fún Àlejò rẹ, Olóri-Ogun àkọ́kọ́ Aguiyi Ironsi: Fifty years’ celebration of Late Lt. Col. Adekunle Fajuyi an epitome of Loyalty

Yorùbá fẹ́ràn àlejò púpọ̀.  Ìwà ti ọmọ ilú lè hù ti yio fa ibinú, bi àlejò bá hu irú ìwà bẹ́ ẹ̀, wọn yio ni àlejò ni, ki wọn fori ji i.  Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Ojú àlejò ni a ti njẹ igbèsè, ẹhin rẹ  la nsaán”.  Eyi fi hàn bi Yorùbá ti  fẹ́ràn  lati ma ṣe àlejò tó.

Ìbàdàn ni olú-ilú ipinlẹ̀ Yorùbá ni Ìwọ̀-Oorun Nigeria tẹ́lẹ̀ ki Ìjọba Ológun ti Aguiyi Ironsi ti jẹ Olóri tó kó gbogbo ipinlẹ̀ Nigeria pọ si aarin lẹhin ti wọn fi ibọn gba Ìjọba lọ́wọ́ Òṣèlú ni aadọta ọdún sẹhin. Lẹhin oṣù keje ni aadọta ọdún sẹhin, àwọn Ológun fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji.  Ti àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nigbati wọn fi ibọn lé àwọn Òṣèlú àkọ́kọ́ lẹhin òmìnira kúrò ni ọjọ́ karùndinlógún, oṣù kini ọdún Ẹdẹgbaalemẹrindinlaadọrin.  Lẹhin oṣù meje, àwọn Ológun tún fi ibọn gbà Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Ológun ti wọn fi ibọn gbé wọlé ti Aguiyi Ironsi jẹ olóri rẹ.  Lára Ìjọba Ológun àkọ́kọ ti Ọ̀gágun Aguiyi Ironsi ti jẹ́ Olóri Ìjọba ni wọn ti fi Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi  jẹ Olóri ni ipinlẹ̀ Yorùbá dipò Òṣèlú Ládòkè Akintọ́lá ti àwọn Ológun pa.

Military incursion in Nigeria - 1966

Military incursion in Nigeria – 1966

Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi gba Olóri-ogun Aguiyi Ironsi ni àlejò ni ibùgbé Ìjọba ni Ìbàdàn nigbati àwọn Ológun dé lati fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji.   Nigbati àwọn Ajagun dé lati gbé Olóri Ogun Aguiyi Ironsi lọ, gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá, Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi bẹ̀bẹ̀ ki wọn fi àlejò òhun silẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kọ.  Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fi ara rẹ ji pé ti wọn ba ma a gbee,  ki wọn gbé òhun pẹ̀lú.  Nitori eyi àwọn Ológun gbe pẹ̀lú àlejò rẹ wọn si pa wọ́n pọ ni Ìbàdàn.

Ni ọjọ́ kọkandinlọgbọn oṣù keje ọdún Ẹgbàálémẹ́rindinlógún, ilú péjọ pẹ̀lú ẹbi àti ará ni Adó-Èkìtì lati ṣe iranti Olóògbé Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fún iranti iwà iṣòótọ ti ó hù titi dé ojú ikú pẹ̀lú àlejò àti ọ̀gá rẹ Olóri Ogun Aguiyi Ironsi ni aadọta ọdún sẹhin.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-07-29 22:27:39. Republished by Blog Post Promoter