Tag Archives: Law abiding

“A ki i jẹ Igún, a ki i fi Ìyẹ́ Igún rinti: Ẹnu Ayé Lẹbọ” – “It is forbidden to eat the Vulture or use its feather as cotton bud: One should be careful of what others say”

Ohun ti o jẹ èèwọ̀ tàbi òfin ni ilú kan le ma jẹ èèwọ̀/òfin ni ilú miran ṣùgbọ́n bi èniyàn bá dé ilú, ó yẹ ki ó bọ̀wọ̀ fún àṣà àti òfin ilú.  Bi èniyàn bá ṣe nkan èèwọ̀, ó lè ṣé gbé ti kò bá si ẹlẹri lati ṣe àkóbá tàbi ki ó fi ẹnu ṣe àkóbá fún ara rẹ̀.

Ni ilú kan ti a mọ̀ si “Ayégbẹgẹ́”, àwọn àlejò ọkùnrin meji kan wa ti orúkọ wọn njẹ́ – Miòṣé àti Moṣétán.  Ọba ilú Ayégbẹgẹ́ kede pé èèwọ̀ ni lati jẹ ẹiyẹ Igún ni ilú wọn.  Akéde ṣe ikilọ̀ pé ẹni ti ó bá jẹ Igún, ikùn rẹ yio wu titi yio fi kú ni.  Àwọn àlejò meji yi ṣe ìlérí pé kò si nkan ti yio ṣẹlẹ̀ ti àwon bá jẹ Igún, nitori eyi wọn fi ojú di èèwọ̀ ilú Ayégbẹgẹ́.

Igún - Vulture

Igún – Vulture

Miòṣé, lọ si oko, ó pa Igun, ó din láta, ó si jẹ́, ṣùgbọ́n ó pa adiẹ, ó da iyẹ́ adiẹ si ààtàn bi ẹni pé adiẹ ló jẹ.  Ọ̀pọ̀ ará ilú ti wọn mọ̀ pé èèwọ̀ ni lati jẹ Igún paapa, jẹ ninú rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mọ pé Igún ni àwọn jẹ, wọn rò wi pé adiẹ ni.  Miòṣé fi ọ̀rọ̀ àṣiri yi sinú lai si nkan ti ó ṣe gbogbo àwọn ti ó jẹ Igún pẹ̀lú rẹ.

Moṣétán lọ si oko ohun na a pa Igun, ó gbe wá si ilé, ṣùgbọ́n kò jẹ́.  Ó pa adiẹ dipò Igún, o din adiẹ ó jẹ ẹ, ṣùgbọ́n, ó da iyẹ́ Igún si ààtàn bi ẹni pé Igún lohun jẹ.  Ni ọjọ́ keji àwọn ará ilú ri iyẹ́ Igún wọn pariwo pé Moṣétán jẹ èèwọ̀, ó ni bẹni, ohun jẹ Igún.  Ni ọjọ́ kẹta inú Moṣétán bẹ̀rẹ̀ si i wú titi ara fi ni.  Nigbati ìnira pọ̀ fún Moṣétán, ó jẹ́wọ́ wi pé adiẹ lohun jẹ, ṣùgbọ́n wọn ko gba a gbọ pé kò jẹ Igun, titi ti ó fi ṣubú ti ó si kú. Yorùbá ni “Ẹnu Ayé Lẹbo”, Moṣétán fi ẹnu kó bá ara rẹ̀.

Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pé, àfojúdi kò dára, ó yẹ ki enia pa òfin mọ nitori “Bi a ti nṣe ni ilé wa, èèwọ̀ ibò miran”.  Ẹni ti kò bá pa òfin mọ, á wọ ijọ̀ngbọ̀n ti ó lè fa ikú tàbi ẹ̀wọ̀n.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-29 23:20:09. Republished by Blog Post Promoter