Tag Archives: Late Prof. Olikoye Ransome-Kuti

“Orúkọ ti òbi Yorùbá nsọ Àbíkú” – “Yoruba parental names associated with Child Mortality”.

(Olóògbé Ọ̀jọ̀gbọ́n Olikoye Ransome Kuti – Oníṣègùn-Ọmọdé ti gbogbo àgbáyé mọ̀, Òjíṣẹ́-Òṣèlú Nigeria ni ọdún keji-din-lọ́gbọ̀n si ọdún keji-lé-lógún sẹhin, ṣe irànlọ́wọ́ gidigidi nipa di-din “Ikú ọmọdé kù” nipa ẹ̀kọ́-ìlàjú fún gbogbo ilú àti abúlé.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ni, ìlàjú lóri ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsi gbàlà lọ́wọ́ ikú igbẹ́-gburu, nipa ìmọ̀ “Omi Oni-yọ lati dipò omi ara”.

Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ bi Àbíkú ti din-ku ni orilẹ̀ èdè Nigeria, nitori eyi orúkọ Àbíkú din-kù:

Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún mẹrin-lé-lógún sẹhin jẹ́ Igba-lé-mẹ́tàlá
Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún keji sẹhin ti din-kù si Mẹrin-lé-lọgọfa.

ENGLISH TRANSLATION

 An Internationally acclaimed Paediatrician, Late Professor Olikoye Ransome-Kuti – Nigeria’s Minister of Health 1986 to 1992 contributed greatly to the reduction of Child Mortality in Nigeria through his Television/Radio Enlightenment Programme as well as promotion of Rural Health Education.  Many children were saved from death through diarrhoea through his Television and Radio Enlightenment Programme on “Oral Dehydration Therapy – ORT”.

Check out example of how Child Mortality has reduced in Nigeria, hence names associated with Child Mortality has reduced.  According to UNICEF statistics:

Under 5 Mortality Rate (U5MR) 1990 – 213
Under 5 Mortality Rate (U5MR) 2012 – 124

 

 Orúkọ Yorùbá fú́n Àbíkú  – Yoruba Name associated with child-mortality

 

 Igé Kúrú Orúkọ Àbíkú – Short form of Name associated with child-mortality

 

  

Itumọ – Meaning in English

Gbókọ̀yi Kọyi The forest rejected this
Kòkúmọ́ Kòkú Not dying again
Malọmọ Malọ Do not go again
Igbẹkọyi Kọyi The dungeon rejected this
Akisatan No more rags (worn out clothes or rags were used as diapers)
Kòsọ́kọ́ No hoe (e.g. hoe is synonymous with any instrument used in digging the grave i.e. Digger, Shovel, etc
Ọkọ́ya The hoe is broken (i.e. hoe is synonymous with any digging instruments)
Ẹkúndayọ̀ Dayọ̀ Weeping has turned to joy
Rẹ̀milẹ́kún Rẹmi Pacify me from weeping
Ògúnrẹ̀milẹ́kún Rẹ̀milẹ́kún The god of iron (Ogun) has pacified me from weeping
Olúwarẹ̀milẹ́kún Rẹ̀mi/Rẹ̀milẹ́kún God has pacified me from weeping
Bámitálẹ́ Tálẹ́ Remain with me till the evening/end
Fadaisi/Fadayisi Daisi/Dayisi “Ifa” has spared this
Ogundaisi/Ogundayisi Daisi/Dayisi “Ogun” has spared this
Mátànmijẹ Mátànmi Don’t deceive me
Jokotimi Joko Seat with me
Dúrójayé Dúró/Jayé Stay to enjoy the world
Dúró́sinmi Dúró/Sinmi Stay to bury me (Me here means the plea from the child’s parent)
Dúróorikẹ Rikẹ Stay to bury me (Me here means the plea from the child’s parent)
Dúrótimi Rotimi Stay with me
Bámidúró Dúró Stand with me
Jokotọla Joko/Tọla Seat with wealth
Adérọ́pò Rọ́pò He/she who came to replace
Olúwafirọ́pò Rọ́pò/Firọ́pò God’s replacement
Dúródọlá Dúró/Dọlá Wait for wealth
Kilanko Lanko What are we naming
Ajá Dog
Ẹnilọlóbọ̀ Ẹnilọ He/she who left has returned
Dúrójogún Dúró/Jogún Live/Stay to inherit.
Share Button

Originally posted 2014-09-23 09:01:44. Republished by Blog Post Promoter