Tag Archives: Late Okunade Sijuwade

Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Ọba Okùnadé Alade Sijúwadé, Olúbùṣe Keji Wàjà – The Ooni of Ife, King Okunade Alade Sijuwade has joined his Ancestors

Olóògbé Ọba Sijúwadé Olúbùṣe Keji - Late King Sijuwade, Olubuse II.

Olóògbé Ọba Sijúwadé Olúbùṣe Keji – Late King Sijuwade, Olubuse II.

Ni ọjọ Kejidinlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún Ẹgbãlemẹ͂dógún, iroyin jade ninú àwọn iwé-iroyin àti ori ayélujára pé Ọba Okunade Sijuwade, Olúbùṣe Keji, pa ipò da ni Ilú Ọba.  Àwọn Olóyè Ilé-Ifẹ̀ sẹ́ ọ̀rọ̀ ikú Ọba yi, nitori ni ayé àtijọ́, àwọn àgbà Oyè ló ni àṣẹ lati tú ọ̀fọ̀ pé Ọba wàjà fún ará ilú, nitori gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá Ọba ki kú.  Àwọn àgbà Oyè tú ọ̀fọ̀ ni iwá́jú Gómìnà Rauf Arégbẹ́ṣọlá ti ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun, ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kejila oṣù kẹjọ ọdún Ẹgbãlemẹ͂dógún. Ni ayé òde òni kò si àṣiri mọ, àṣà yi ti yi padà nitori, ni àtijọ́, Ọba ki kú si àjò, bẹni kò si iwé-iroyin àti ẹ̀rọ ayélujára.

Ilé Ifẹ̀ jẹ́ ilú pàtàki ni ilẹ̀ Yorùbá nitori itàn sọ wi pé ibẹ̀ ni orisun Yorùbá pẹ̀lú Bàbá nla Yorùbá “Oduduwa” ti ó tẹ ibẹ̀ dó.   Okùnadé Alade Sijúwadé, Olúbùṣe Keji, gun ori oyè Ọọni Ifẹ̀ nigbati ó pé aadọta ọdún, ó lo ọdún mẹ͂dógóji ni ipò Ọọni Ifẹ̀.  Ohun ni aadọta Ọba Ilé Ifẹ̀.

Ìsìnkú Ọba Sijúwadé bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kẹrinla, oṣù Kẹjọ, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún.  Lẹhin ìsìnkú, ìséde ọlọ́jọ́ meje yio bẹ̀rẹ̀ ni Ilé-Ifẹ̀ àti agbègbè rẹ lati agogo mẹrin ìrọ̀lẹ́. Ki Èdùmàrè gba olóògbé Ọba Sijúwadé si afẹ́fẹ́ rere.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button