Tag Archives: Killing by Herdsmen

A ò lè tori a mà jẹran dọ̀bálẹ̀ fún Mãlu – Àgbẹ́kọ̀yà kọ Àṣejù Fúlàní Darandaran – Agbekoya (meaning Farmers reject oppression) condemn the excesses of Fulani Herdsmen

Ìròyìn tó gbòde, ni ọ̀rọ̀ Ìjọba-àpapọ̀ ti ó fẹ ki gbogbo ìpínlẹ̀ ni Nigeria pèsè àyè ni ọ̀fẹ́ fún àwọn darandaran lati tẹ̀dó dípò ki wọn ma kó Mãlu kiri.

Ni ipinlẹ si ìpínlẹ̀, oníkálùkù lò ni iṣẹ́ tàbi òwò tirẹ̀.  Iṣẹ́ àgbẹ̀ ló wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá ni ayé àtijọ.  Bi iṣẹ́ àgbẹ̀ ti ṣe pàtàki fún Yoruba, bẹ ni ise darandaran jẹ́ fún Fúlàní ni òkè-ọya.  Ìyàtọ̀ ti ó wà ni àwọn iṣẹ́ mejeeji ni wi pé, àgbẹ̀ ńṣe oko ni agbègbè rẹ, nigbati darandaran ńda ẹran wọn kakiri lati ìlú kan si ekeji.

Ilẹ̀ pọ̀ ju èrò lọ ni oke- ọya ju odò-ọya lọ. Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “A o ri ibi sùn, ajá ńhanrun”.  Ìjà Sèríà àti Boko Haram ti ṣi ọpọlọpọ ni idi kúrò ni òkè-ọya bọ́ si odò-ọya.    Àyè kò tó fún ogúnlọ́gọ̀ ènìyàn ti ó ngbé ni odò-ọya pàtàki fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ó dari wále nitori ija Bókó Haram àti ogun abẹ́lé yoku ni òkè-ọya.

Fúlàní Darandaran – Fulani Herdsman

Yorùbá fẹran àlejò púpọ̀, darandaran ti nda ẹran wá si ilẹ̀ Yorùbá lai si ìjà, ọ̀na ti jin. Ọba, Ìjòyè àti ọlọ́rọ̀ àyè àtijọ́ ma nni agbo ẹran tàbi Mãlu ti àwọn Fúlàní mba wọn tọ́jú.  Ibùjẹ-ẹran tún wà ni ilẹ̀- Yorùbá ni Àkùnnù-Àkókó. Ni ayé òde òni, kò bójú mu lati da ẹran kiri ni igboro àti ilú nlá.    Di da ẹran kiri ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàmbá ọkọ̀ tó ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí lọ.  Ki ẹran má a jẹ ohun ọ̀gbìn àgbẹ̀ àti ba oko jẹ kò bójú mu.  Èyí ti ó́ burú ju ni darandaran ti ó ngbé ìbọn dání dípò ọ̀pá-ìdaran, ti wọn ti pa olóko tori ki malu lè jẹun.  Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “A ò lè tori a ma jẹ́ran, dọ̀bálẹ̀ fún Mãlu”, eleyi ló jẹ́ ki ẹgbẹ́ Àgbẹ́kọ̀yà kọ ètò ìjọba àpapọ̀ lati pèsè ilẹ̀-ọ̀fẹ́ fún àwọn Fulani ti ó nda ẹran ni ipinle Yorùbá àti lati kọ ìyà lọ́wọ́ daran-daran ti o ngbé ìbọn lati da ẹran.

Ni ilú òyìnbó, àgbẹ àti àwọn ti o ńsin ẹran nri ìrànlọwọ gbà ni ọdọ Ìjọba. Ó yẹ ki ijoba apapo pèsè irinṣẹ́ ìgbàlódé fún àwọn àgbẹ̀ àti ki àwọn ipinlẹ̀ pèsè àyè rẹpẹtẹ fún oko lati gbin oúnjẹ fún àwọn ogúnlọ́gọ̀ èrò ti ó pọ̀si odò-ọya ju ìpèsè ilé ọ̀fẹ́ fún darandaran.   Ìmọ̀ràn fún Ìjọba-àpapọ̀ ni ki wọn lo ilẹ̀ ti ó pọ̀ rẹpẹtẹ ni òkè-ọya pàtàki igbó Sambisa ti àwọn Bókó Haram fi ṣe ibùjòkó tẹ́lẹ̀ ki Ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́ tó lé wọn jade fun agbo malu.

ENGLISH TRANSLATION

The current news in Nigeria is the Federal Government’s directives for the States to voluntarily give land for herdsmen’s colony to stem the current practice of herdsmen moving from place to place for grazing.  Continue reading

Share Button