Tag Archives: Fall of Naira

“Ayẹyẹ ṣi ṣe ni Òkèrè – Àṣà ti ó mba Owó Ilú jẹ́”: “Destination Events – The Culture that is destroying the Local Currency”

Yorùbá fẹ́ràn ayẹyẹ ṣi ṣe púpọ̀ pàtàki fún igbéyàwó.  Ni ayé àtijọ́, ìnáwó igbéyàwó kò tó bi ó ti dà ni ayé òde òni.  Titi di bi ogoji ọdún sẹhin, ilé Bàbá Iyàwó tàbi ọgbà ẹbi ni wọn ti nṣe àpèjọ igbéyàwó.  Ẹbi ọ̀tún àti ti òsi yio joko fún ètò igbéyàwó lati gba ẹbi ọkọ ni àlejò fún àdúrà gbi gbà fún àwọn ọmọ ti ó nṣe igbéyàwó àti lati gbà wọn ni ìyànjú bi ó ṣe yẹ ki wọn gbé pọ̀ ni irọ̀rùn.  Ẹbi ọkọ yio kó ẹrù ti ẹbi iyàwó ma ngbà fún wọn, lẹhin eyi, ẹbi iyàwó yio pèsè oúnjẹ fún onilé àti àlejò.  Onilù àdúgbò lè lùlù ki wọn jó, ṣùgbọ́n kò kan dandan ki wọn lu ilu tàbi ki wọn jó.

Nigbati ìnáwó rẹpẹtẹ fún igbeyawo bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹlòmíràn bẹ̀rẹ̀ si jẹ igbèsè lati ṣe igbéyàwó pàtàki igbéyàwó ti Olóyìnbó ti a mọ si igbéyàwó-olórùka.  Nitori àṣejù yi, olè bẹ̀rẹ̀ si jà ni ibi igbéyàwó, eyi jẹ́ ki wọn gbé àpèjẹ igbéyàwó àti àwọn ayẹyẹ yoku kúrò ni ilé.  Wọn bẹ̀rẹ̀ si gbé àpèjẹ lọ si ọgbà ilé-iwé, ilé ìjọ́sìn tàbi ọgbà ilú àti ilé-ayẹyẹ.

Yorùbá fẹ́ràn ayẹyẹ ṣi ṣe púpọ̀, ṣùgbọ́n àṣà tó gbòde ni ayé òde òni, ni igbéyàwó àti ayẹyẹ bi ọjọ́ ìbí ṣi ṣe ni òkèrè.  Gẹgẹ bi àṣà Yorùbá, ibi ti ẹbi iyàwó bá ngbé ni ẹbi ọkọ yio lọ lati ṣe igbéyàwó.  Ẹni ti kò ni ẹbi àti ará tàbi gbé ilú miran pàtàki Òkè-Òkun/Ilú Òyìnbó, yio lọ ṣe igbéyàwó ọmọ ni òkèrè.  Wọn yio pe ẹbi àti ọ̀rẹ́ ti ó bá ni owó lati bá wọn lọ si irú igbéyàwó bẹ́ ẹ̀.  Ẹbi ti kò bá ni owó, kò ni lè lọ nitori kò ni ri iwé irinna gbà.  A ri irú igbéyàwó yi, ti ẹbi ọkọ tàbi ti iyàwó kò lè lọ.  Eleyi wọ́pọ laarin àwọn Òṣèlú, Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ Ìjọba àti àwọn ti ó ri owó ilú kó jẹ.

Igbéyàwó àti ayẹyẹ ṣi ṣe ni òkèrè, jẹ́ ikan ninú àṣà ti ó mba owó ilú jẹ́.   Lati kúrò ni ilú ẹni lọ ṣe iyàwó tàbi ayẹyẹ ni ilú miran, wọn ni lati ṣẹ́ Naira si owó ilu ibi ti wọn ti fẹ́ lọ ṣe ayẹyẹ, lẹhin ìnáwó iwé irinna àti ọkọ̀ òfúrufú.  Ilú miran ni ó njẹ èrè ìnáwó bẹ́ ẹ̀, nitori bi wọn bá ṣe e ni ilé, èrò púpọ̀ ni yio jẹ èrè, pàtàki Alásè àti Onilù.  A lérò wi pé ni àsìkò ọ̀wọ́n owó pàtàki owó òkèrè ni ilú lati ṣe nkan gidi, ifẹ́ iná àpà fún ayẹyẹ á din kù.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-04-26 18:55:23. Republished by Blog Post Promoter