Tag Archives: Corrupt Politicians

“Awọ kò ká Ojú ìlù, Ọmọ Onílù ni òhun fẹ́ má a sun Awọ jẹ – Ojúkòkòrò àwọn Òṣèlú Nigeria”: “Not enough Leather for drum making, the drummer boy is craving for leather meat delicacy: Greedy Nigerian Politicians”

Nigbati àwọn Òṣèlú gba Ìjọba ni igbà keji lọ́wọ́ Ìjọba Ológun, inú ará ilú dùn nitori wọn rò wi pé Ológun kò kọ iṣẹ́ Òṣèlú.  Ilú rò wi pé Ìjọba Alágbádá yio ni àánú ilú ju Ìjọba Ológun lọ.  Ó ṣe ni laanu pé fún ọdún mẹ́rìndínlógún ti Òṣèlú ti gba Ìjọba, wọn kò fi hàn pé wọn ni àánú ará ilú rárá.  Dipò ki wọn ronú bi nkan yio ti rọrùn fún ilú nipa ipèsè ohun amáyédẹrùn bi iná mọ̀nàmọ́ná, ilé-iwé, ilé-ìwòsàn, ojú ọ̀nà ti ó dára, òfin lati jẹ ki ilú tòrò, ṣe ni wọn bẹ̀rẹ̀ si ji owó ilú.  Bi ori bá fọ́ Òṣèlú, wọn á lọ si Òkè-Òkun nibiti wọn kó owó ti ó yẹ ki wọn fi tú ilé-ìwòsàn ṣe si.  Àwọn Òṣèlú Òkè-Òkun nfi owó Nigeria tọ́jú ará ilú wọn nitori eyi, gbogbo ọ̀dọ́ Nigeria ti kò ni iṣẹ́ fẹ́ lọ si Òkè-Òkun ni ọ̀nà kọnà.

Ọmọ Onilù - The Drummer. Courtesy: theyorubablog

Ọmọ Onilù – The Drummer. Courtesy: theyorubablog

Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Awọ kò ká Ojú ìlù, Ọmọ Onilù ni òhún fẹ́ má a sun Awọ jẹ” bá ìròyìn ti ó jáde ni lọ́wọ́-lọ́wọ́, bi àwọn Òṣèlú ti bá owó ọrọ̀ ajé Nigeria jẹ nipa bi wọn ti ṣe pin owó ohun ijà fún Ológun lati ra ibò.  ‘Epo Rọ̀bì’ ni ‘Awọ’ nitori ó lé ni idá ọgọrin ti owó epo rọ̀bì kó ni owó ọrọ̀ ajé ti ilú tà si Òkè-Òkun.  Fún bi ọdún mẹ̃dógún ninú ọdún merindinlogun ti Èrò Ẹgbẹ́ Òṣèlú (ti Alágboòrùn) fi ṣe Ìjọba ki ó tó bọ lọ́wọ́ wọn ni ọdún tó kọjá, owó epo rọ̀bì lọ si òkè rẹpẹtẹ, ọrọ̀ ajé yoku pa owó wọlé.  Dipò ki wọn lo owó ti ó wọlé lati tú ilú ṣe, wọn bẹ̀rẹ̀ si pin owó lati fi ra owó Òkè-Òkun lati kó jade lọ ra ilé nlá si àwọn ilú wọnyi lati sá fún ilú ti wọn bàjẹ́ ni gbogbo ọ̀nà.

Owó epo rọ̀bì fọ́, awọ kò wá ká ojú ilú mọ́.  Oníṣẹ́ Ìjoba kò ri owó-oṣ̀ù gbà déédé, àwọn ti ó fi ẹhin ti ni iṣẹ́ Ìjọba kò ri owó ifẹhinti wọn gba, owó ilú bàjẹ́, bẹni àwọn Òṣèlú bú owó oṣ́u rẹpẹtẹ fún ara wọn.  Eyi ti ó burú jù ni owó rẹpẹtẹ miran ti wọn bù lati ra ọkọ ti ìbọn ò lè wọ, olówó nla lati Òkè-Òkun fún Ọgọrun-le-mẹsan Aṣòfin-Àgbà.   Olóri Aṣòfin-Àgbà fẹ ra ọkọ̀ mẹsan fún ara rẹ nikan.

Àsìkò tó ki àwọn èrò ji lati bá àwọn olè wọnyi wi, nitori àwọn Òṣèlú Òkè-Òkun nibiti wọn nkó owó ilú lọ, kò fi owó ilú wọn tọ́jú ara wọn, wọn nwọ ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ilú, àyè kò si fún wọn lati ja ilú ni olè bi ti àwọn Òṣèlú Nigeria.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-02-19 10:12:16. Republished by Blog Post Promoter