Tag Archives: Charleston Church Massacre

“Oníkùn ló mọ ìkà” – Dylann Roof wọnú Ìjọ Aláwọ̀dúdú pa eniyan mẹsan lai ṣẹ: “Only one knows what is going on within” – Charleston Church Massacre

Ilé Ìjọ́sìn jẹ ibi ti kò yẹ kó kọ ẹnikẹni, nitori eyi, onírú́urú eniyan ló npe jọ fún ẹ̀sìn ṣùgbọ́n, itàn fi hàn pé, ilú àti agbègbè ti iṣẹ̀lẹ̀ burúkú yi ti wáyé, kò ri bẹ ẹ.  Ni ayé àtijọ́. Funfun kò gbà ki dúdú ba wọn pé jọ ni ilé Ìjọ́sìn kan na a.  Eleyi ló jẹ́ ki Aláwọ̀dúdú America kó ra jọ lati bẹ̀rẹ̀ ilé Ìjọ́sìn ti wọn.  Itàn tún fi hàn pé, ọjọ́ Ìsimi ló burú jù fún Aláwọ̀dúdú America nitori bi àwọn Aláwọ̀funfun miran ti nkúrò ni ilé Ìjọ́sìn ni wọn nwa Aláwọ̀dúdú ti wọn yio pa.

Ìjọ Aláwọ̀dúdú – Emmanuel African Methodist Church – Scene of the Massarce

Ọrọ igbàgbọ́ ni “Ìkúnlẹ̀ wá dọ́gba, ṣùgbọ́n ibere wá yàtọ̀”, eyi túmọ̀ si wi pé kò si ẹni tó lè mọ èrò inu ẹnikeji.  Ni irọlẹ, ọjọ́ kẹtàdìnlógún, oṣù kẹfa, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún, àwọn bi mẹ́tàlá pé jọ si ilé Ìjọ́sìn Aláwọ̀dúdú lati kọ́ ẹ̀kọ́ Bibéli àti lati gbàdúrà, ọkùnrin Aláwọ̀funfun Dylann Roof, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún, wọlé si ibi ipéjọ yi.  Gẹ́gẹ́ bi ìṣe Aláwọ̀dúdú, wọn ò kọ ẹnikẹ́ni ni ilé Ìjọ́sìn, wọn kò fura si nitori ó jẹ Aláwọ̀funfun, ó joko tó wákàtí kan laarin wọn kó tó bẹ̀rẹ̀ si yin ìbọn lati pa àwọn to ́péjọ.

Dylann Roof pa Aláwọ̀dúdú mẹsan lai ṣe, nitori ó korira Aláwọ̀dúdú.  Ó ṣe iṣẹ́ ibi yi tan, ó sá, ṣùgbọ́n ọwọ́ Ọlọpa ti ba a, ó si ti jẹ́wọ́ pé òhun ṣe nitori ki “Ogun lè bẹ́ silẹ̀ laarin Aláwọ̀funfun àti Aláwọ̀dúdú”.  Àwọn Ọlọpa ti fi ẹ̀sùn ipaniyan mẹsan kan.  Ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ kọkàndinlógún, oṣù kẹfa, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún.

Ki Ọlọrun tu gbogbo idilé àwọn mẹsan ti wọn gé ayé rẹ kúrú lai ṣe ninú, ki ó si fún wọn ni ìsimi ayérayé.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button