Tag Archives: Benefits

Àjùmòbí kò kan tãnu… Same parentage does not compel compassion…

Ajumomobi o ko ti anu

Same parentage does not compel compassion.

Òwe Yorùbá ní “Àjùmòbí kò kan tãnu, ẹni Olúwa  bá rán síni ló nṣeni lõre”.  Òwe yi wúlò lati gba àwọn ènìà tí o gbójúlé ẹbí níyànjú.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò wípé ẹ̀tọ́ ni ki ẹni tí ó bá lówó nínú ẹbí tàbí tí ó ngbe ni Òkè-Òkun bá wọn gbé ẹrù lai ro wípé ẹbí tí o lówó tàbí gbé l’Ókè-Òkun ní ẹrù tiwọn lati gbé.

Yorùbá ní “Òṣìṣẹ́ wa lõrun, abáni náwó wà níbòji”, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí wọnyi, ma mba ẹni tí o nṣiṣẹ ka owó lai rò wípé ẹni tí ó nṣiṣẹ yi, nlãgun lati rí owó.  Iṣẹ́ lẹ́ni tí ó wa l’Ókè-Òkun/Ìlú-Òyìnbó nṣe nínú òtútù.  Fún àpẹrẹ: níbití olówó tàbí àwọn tí ó ngbe Òkè-òkun tí nṣe àwọn nkan níwọnba bí – ọmọ bíbí, aṣo rírà, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, àti bẹ̃bẹ lọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí á bímọ rẹpẹtẹ, kó owó lé aṣọ, bèrè ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ olówó nla tí ẹni tí ó wà l’Ókè-Òkun ó lè kó owó lé lórí àti gbogbo àṣejù míràn.

Ẹbí olówó tàbí tí ó ngbe Òkè-òkun kò lè dípò Ìjọba.  Ọ̀dọ̀ Ìjọba tí ó ngba owó orí lóyẹ kí á ti bèrè ẹ̀tọ́, ki ṣe lọ́wọ́ ẹbí.  Ẹbí tóní owó tàbí gbé Òkè-òkun lè fi ojú ãnu ṣe ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ki ṣe iṣẹ́ ẹni bẹ̃ lati gbé ẹrù ẹlẹ́rù.   Ẹjẹ́ ká rántí òwe yi wípé “Àjùmọ̀bí kò kan tãnu, ẹni Olúwa bá rán síni ló nṣeni lõre”, nítorí aladugbo, àjòjì, ọ̀rẹ́, àti bẹ̃bẹ lọ, lè ṣeni lãnu bí Olúwa bá rán wọn.

ENGLISH TRANSLATION

A Yoruba saying goes that “same parentage does not compel compassion, only those sent by God show compassion”.  This proverb can be used to advice those dependent on family member.  Many dependents think it is a right for rich or family members living abroad to carry their responsibilities. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-18 18:00:26. Republished by Blog Post Promoter

Ìṣe Ilé ló mbá ni dode – Trudy Alli-Balogun ja Ilé-Iṣẹ́ rẹ lólè – The character cultivated at home often reflect in the public – Trudy Alli-Balogun a Council Officer jailed for £2.4 million housing fraud

Ìbá ṣe pọ̀ laarin Yorùbá àti Ìlú-Ọba ti lé ni igba ọdún nitori òwò Òkè-òkun, pàtàki òwò ẹrú àti fún ẹ̀kọ́ ni ilé iwé giga.  Nitori eyi, àṣà àti èdè Yorùbá kò ṣe fi ọwọ́ rọ sẹhin.

fraud.jpg

Trudy Alli-Balogun jailed for 5 years over £2.4 million housing fraud

Ni Ilú-Ọba, ẹ̀tọ́ ará ilú ni ki Ìjọba pèsè ohun amáyédẹrùn, pàtàki ibùgbé fún ọmọ ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́ fún ọmọ àti ará ilú.  Àwọn ẹ̀tọ́ wọnyi kò tọ́ si àlejò, ẹni ti ó fi èrú wọ ilú ti kò ni àṣẹ igbelu, tàbi ẹni tó ni iwé lati ṣe iṣẹ ṣùgbọ́n ko ti i di ará ilú.  Ẹni ti ó ni iwé-igbelu lati ṣe iṣẹ́ ti ko ti di ará ilú kò ni ẹ̀tọ́ si ilé Ìjọba, ṣùgbọ́n wọn ni ẹ̀tọ́ si ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́. Iwé ìròyìn irọlẹ, gbe jade bi Trudy Alli-Balogun, ti lo ipò rẹ ni ilé iṣẹ́ ti ó nṣe ipèsè ibùgbé fún ọmọ ilú, lati gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Yorùbá ti kò ni ẹ̀tọ́ si irú ilé bẹ́ ẹ̀.  Wọn ṣe ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún marun fún.

Ìròyìn ti ó gbòde ni inu iwé ìròyìn  àti lori ayélujára fi han bi àwọn Olóri Òṣèlú, Aṣòfin àgbà nla àti kékeré, òṣiṣẹ́ Ìjọba àgbà àti àwọn ti ó wà ni ipó giga ni Nigeria ti lo ipò wọn lati fi ja ilu lólè.  Àyipadà ni Ìjọba pẹ̀lú pe Olóri Òṣèlú Muhammadu Buhari/Yẹmi Osinbajo ti ó gbógun ti iwà ibàjẹ́, ló jẹ ki àṣiri iṣẹ́ ibi wọnyi jade si ará ilú bi àwọn ti ó  wà ni ipò giga ti nlo ipò lati fi hu iwà ibàjẹ́ nitori àti kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà ẹ̀bùrú.

Yorùbá sọ wi pé “Ìṣe ilé ló mbá ni dode”.  Ni àtijọ́, àṣà Yorùbá ni lati wá idi bi enia ti kó ọrọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ni ayé òde oni, olówó ni wọ́n mbọ, bi ó bá ti ẹ jalè tàbi ti ẹ̀wọ̀n de nitori iṣẹ́ ibi.  Àyipadà burúkú yi ni obìnirin Trudy Alli-Balogun gbé dé ẹnu iṣẹ́ lati ja ilé iṣẹ́ rẹ ni olè ọ̀kẹ́ aimoye, ti ó si na owó bẹ́ ẹ̀ ni ìná àpà lai ronú orúkọ burúkú ti ó rà fún Yorùbá àti gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria ni Ilú-Ọba àti pé irú iwà ibàjẹ́ yi ló ba ohun amáyédẹrùn jẹ ni Nigeria.  Iwà ibàjẹ́ kò ni orúkọ meji, ẹni ba jalè ba ọmọ jẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-05-06 23:39:56. Republished by Blog Post Promoter