Tag Archives: Anguish of mind

Àròkàn ló n fa ẹkún à sun à i dákẹ́: Anguish of mind is the root cause of uncontrollable cry

Ohun ti Yorùbá mọ̀ si àròkàn n irònú igbà gbogbo.  Kò si ẹni ti ki ronú, ṣùgbọ́n àròkàn léwu.  Inú rirò yàtọ si àròkàn. Inu rirò ni àwọn Onimọ-ijinlẹ̀ lò lati ṣe ọkọ̀ òfúrufú tàbi lọ si òṣùpá, oògùn igbàlódé lati wo àisàn, àti fún ipèsè ohun amáyédẹrùn igbàlódé yoku ṣùgbọ́n  àròkàn lo nfa pi-pokùnso, ipàniyàn, olè jijà àti iwà burúkú miran.

Bi èniyàn bá lówó tàbi wa ni ipò agbára kò ni ki ó má ro àròkàn nitori ìbẹ̀rù ki ohun ini wọn ma

Àròkàn ló fa Ẹkún - Deep thought causes grief

Àròkàn ló fa Ẹkún – Deep thought causes grief

parẹ́, àisàn, ọ̀fọ̀, àjálù, à i ri ọmọ bi, ọmọ ti o n hùwà burúkú àti àwọn oriṣiriṣi idi miran.  Bakan naa ni òtòṣì lè ni àròkàn nitori à i lówó lọ́wọ́ tàbi aini, àisàn, ọ̀fọ̀, ìrẹ́jẹ lati ọ̀dọ̀ ẹni ti ó ju ni lọ, ìrètí pi pẹ́ àti àwọn idi miran.

Lára àmin àròkàn ni: à i lè sùn, à i lè jẹun, ìbẹ̀rù, ẹkún igbà gbogbo, ibànújẹ́ tàbi ọgbẹ́ ọkàn.  Àròkàn kò lè tú nkan ṣe à fi ki ó bá nkan jẹ si.  Ewu ti àròkàn lè fà ni: ẹ̀fọ́rí igbà gbogbo, aisan wẹ́rẹ-wẹ̀rẹ, aisan ẹ̀jẹ̀ riru, òyi àti àárẹ̀.

Ni igbà miran kò si ohun ti èniyàn lè ṣe lati yẹ àròkàn pàtàki ẹni ti ọ̀fọ̀ ṣẹ, á ro  àròkàn ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ igbà àwọn ohun miran wà ni ikáwọ́ lati ṣe lati din àròkàn kù.   Lára ohun ti ẹni ti ó bá ni àròkàn lè ṣe ni: ki ó ni igbàgbọ́, ìtẹ́lọ́rùn, ro rere, ṣe iṣẹ rere,  jinà si elérò burúkú tàbi oníṣẹ́ ibi àti lati fẹ́ràn ẹni keji.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-05-23 18:30:49. Republished by Blog Post Promoter