Tag Archives: Akure

“Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì” – “There is no respect for a King that has no Queen”

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Bi ọmọdé bá tó ni ọkọ́, à fún lọ́kọ́”.  Ọkọ́ jẹ irinṣẹ́ pàtàki fún Àgbẹ̀.  Iṣẹ́-àgbẹ̀ ni ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́. Nitori eyi, bi bàbá ti nkọ́ ọmọ rẹ ọkùnrin ni iṣẹ-àgbẹ̀, ni ìyá nkọ́ ọmọ obinrin rẹ ni ìtọ́jú-ile lati kọ fún ilé-ọkọ.  Iṣẹ́ la fi nmọ ọmọ ọkùnrin, nitori eyi, bi ọkùnrin bá dàgbà, bàbá rẹ á fun ni ọkọ́ nitori ki ó lè dá dúró lati lè ṣe iṣẹ́ ti yio fi bọ́ ẹbi rẹ ni ọjọ́ iwájú.

Bi ọkùnrin bá ni iṣẹ́, ó ku kó gbéyàwó ti yio jẹ “Olorì” ni ilé rẹ.  Ìyàwó fi fẹ́ bu iyi kún ọkùnrin, nitori, ó fi hàn pé ó ni igbẹ́kẹ̀lé.  Àṣà Yorùbá gbà fún ọkùnrin lati fẹ́ iye ìyàwó ti agbára rẹ bá gbé lati tọ́jú.  Nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọba, Baálẹ̀, Ìjòyè àti àwọn enia pàtàki láwùjọ ma nfẹ ìyàwó púpọ̀.  Ìṣòro ni ki wọn fi ọkùnrin ti kò ni ìyàwó jẹ Ọba.  Kò wọ́pọ̀ ki Ọba ni ìyàwó kan ṣoṣo.

Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyi Adeṣida - Coronation of the Late Deji of Akure.

Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyi Adeṣida – Coronation of the Late Deji of Akure.

Ohun ti a ṣe akiyesi ni ayé òde òni, ni Ọba ti ó fẹ ìyàwó kan ṣoṣo nitori ẹ̀sìn, pàtàki ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n ti ó ni àlè rẹpẹtẹ.  Ọba ayé òde òni ndá nikan lọ si òde lai mú Olorì dáni.  Gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Yorùbá, “Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì”, nitori eyi, kò bu iyi kún Ọba, ki ó lọ àwùjó tàbi rin irin àjò pàtàki lai mú Olorì dáni.  Ohun ti ó yẹ Ọba ni ki a ri Ọba àti Olorì rẹ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ.

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-11 19:13:42. Republished by Blog Post Promoter

Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó gba Ọ̀pá Àṣẹ Ọba Àkúrẹ́ – Prince Kole Aladetoyinbo receives the Staff of Office as the King of Akure

Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó gba Ọ̀pá Àṣẹ Ọba Àkúrẹ́ - Deji of Akure received Staff of Office

Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó gba Ọ̀pá Àṣẹ Ọba Àkúrẹ́ – Deji of Akure received Staff of Office

Ni ọjọ́ kẹsan oṣù kẹfa, ọdún Ẹgbãlémẹ̃dógún, Olóri-Òṣèlú Gómìnà Olúṣẹ́gun Mimiko ti Ipinlẹ Ondo,   gbé Ọ̀pá Àṣẹ Ọba fún Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó lati di Déjì ilù Àkúrẹ́ kẹrindinlãdọta.

Lẹhin oṣù mejidinlógún ti Ọba Adebiyi Adeṣida pa ipò dà, Àkúrẹ́ kò ni Ọba, a fi Adelé Ọmọba Adétutù Adeṣida Ojei ti ó delé di igbà ti Ọba Kọ́lé Aládétóyìnbó gba Ọ̀pá Àṣẹ.  Bi ó ti ẹ je wi pé Ọba Adebiyi Adeṣida kò pẹ́ lóri oyè ju ọdún mẹta, igbà rẹ tu ilú Àkúrẹ́ lára.

Gẹ́gẹ́ bi ọmọ Àkúrẹ́ pàtàki, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wumi Akintide ti kọ lóri iwé ìròyìn ori ayélujára, nipa “Àwọn idi lati yọ ayọ̀ Ọba tuntun, Déjì Àkúrẹ́ – Ọ̀dúndún Keji”, tọka si pé, ki ṣe àkọ́kọ́ ti wọn pe Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó wálé lati Òkè-òkun lati wa du ipò Ọba.  Eyi ṣẹlẹ̀ ni ọdún mẹwa sẹhin ni igbà ti Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó jẹ́ ikan ninú àwọn Ọmọba mẹ́tàlá lati idilé Òṣùpá ti oyè kan, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ninú àwọn Afọbajẹ ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nitori eyi, wọn kò ṣe bi ó ṣe yẹ.  Wọn kọ́kọ́ yàn “Iléri” ẹni ti ó gbé owó rẹpẹtẹ silẹ̀ lai ṣe iwadi dájú pé Ọmọba ni, nigbati ilú kọ ẹni ti wọn yàn,  wọn pe Ọmọba Adépọ̀jù Adeṣina (ti won ro loye) lati Ilú-Ọba lati fi jẹ Ọba dipò Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó ti ipò Ọba tọ́ si.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Ayé kò lè pa kádàrá dà, ṣùgbọ́n wọn lè fa ọwọ́ aago sẹhin”, lẹhin ọ́dun mẹwa, àwọn Afọbajẹ yan Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó laarin Ọmọba méjìlá lati idile Òṣùpá, ó si gba Ọ̀pá Àṣẹ ni wẹ́rẹ́.

Èdùmàrè á jẹ ki Adé ó pẹ́ lóri, ki bàtà á pẹ́ lẹ́sẹ̀, ki igbà Ọba Kọ́lé Aládétóyìnbó tú ilú Àkúrẹ́ lára”, Àṣẹ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Ẹrú kú ìyá ò gbọ́, ọmọ́ kú ariwo ta – ọ̀fọ̀ ṣe ni ìlú Àkúrẹ́: “The slave died the mother was not informed, a freeborn died, lamentation erupted” – Akure people mourns”

Òkìkí ìròyìn pé Ọba Àkúrẹ́ wàjà (Ọba Adebiyi Adeṣida) kàn ni òwúrọ̀ ọjọ́ Aiku, ọjọ́ kini, oṣu kejila ọdún ẹgbẹwa-le-mẹtala.  Ọmọ ọdún mẹta-le-lọgọta ni Ọba Adeṣida, ó jọba ni ọdún mẹta le diẹ sẹhin, eleyi lo jẹ ki iroyin yi jẹ ọfọ gidigidi.

Gẹgẹ bi òwe Yorùbá yi “Eru ku…., bi o ti le jẹ pe ko yẹ ki irú iroyin bẹ jade titi di ọjọ keje lẹhin ti Ọba bá wàjà, òkìkí ti kan lori ẹ̀rọ ayélujára.

ENGLISH TRANSLATION

http://odili.net/news/source/2013/dec/1/830.html

Deji of Akure dies at 63  by Eniola Akinkuotu

Deji of Akure dies at 63
by Eniola Akinkuotu

The report of the demise of the King of Akure (King Adebiyi Adesida) erupted in the news early morning on Sunday, 1st of December, 2013.  He was aged 63, he reigned barely over three years hence the great mourning of the people.

According to the Yoruba proverb “The slave died the mother was not informed, a freeborn died, lamentation erupted”, even though the news of the king’s demise ought not to have been announced till seven days after his demise, because of his position in the Society, the news was already on the internet.

Share Button