Tag Archives: Additional Yoruba Names

“Bibi ire kò ṣe fi owó rà – Yoruba names” – “Good pedigree cannot be bought with money”

Kò di igbà ti enia bá ni owó rẹpẹtẹ ki ó tó sọ ọmọ rẹ ni “Ọlá” nitori Yorùbá ka ipò giga, ọmọ, ilera, orúkọ rere si “Ọlá”.  Ibi ti “Ọlá” wà ninú orúkọ Yorùbá, a lè lo “Adé; Ibi; Olú; Ọmọ; Oyè” dipò.  Fún àpẹrẹ, “Ọláyẹmi; Adéyẹmi; Ibiyẹmi; Olúyẹmi; Ọmọyẹmi àti Oyèyẹmi”.

ENGLISH TRANSLATION

It is not until a person has so much money before naming a child “Ola which connotes Wealth”, because Yoruba regard, high position in the society, children, good health, good name etc as “Wealth”. Wherever “Ola” appears in a name, it can also be replaced with “Ade – Crown; Ibi – Birth; Omo – Child; Oye – Chieftaincy”.  For example “Olayemi; Adeyemi; Ibiyemi; Oluyemi; Omoyemi and Oyeyemi”.

B TO N       

 

 

 

 Yoruba Names Short Form English meaning
Bọ̀bọ́lá Bọ̀bọ́ Met wealth
Bọ́ládalẹ́ Bọ́lá Remain with wealth till night
Bọlajoko Bọla Seat with wealth
Bọ́lánlé Bọ́lá Met wealth at home
Bọ́látitó Bọ́lá How great the wealth
Dámilọ́lá Dámi Prosper me
Dáramọ́lá Dára Beautiful with wealth
Dúródọlá Dúró Wait for wealth
Dúrótọlá Dúró Wait with wealth
Ẹniọlá Ẹni Wealthy/Prominent Personality
Fadéjimi Jimi Leave the crown with me
Faramádé Mádé Associate with the crown
Faramọ́lá Fara Associate with wealth
Fẹ̀hintọlá Tọlá Lean back on wealth
Fọlábi Fọ́la Came at the time of convenience
Fọlájimi Jimi Leave the wealth with me
Fọláhàn Fọlá Show off wealth
Fọlákẹ́mi Fọlákẹ́ Use wealth to pet me
Fọlámi Fọlá Breathing in wealth
Fọláṣadé Ṣadé Use wealth as crown
Fọláyan Fọlá Boastful in wealth
Fọláyẹmi Yẹmi Let wealth suit me
Fúnmikẹ́/Fúnkẹ́ Funkẹ Given to me to pet
Ibitọ́lá Ibi Birth is equal to wealth
Ikẹ́adé Ikẹ Care of the Crown
Imisiọla Imisi The breath of wealth
Iniọla Ini Ownership of wealth
Iretiọla Ireti Expectation of wealth
Iyiọla Iyi The honour of wealth
Jayéọlá Jayé Enjoy wealth
Jayéọba Jayé Enjoy kingship
Jadesọla Jade Come into wealth
Jokotọla Joko Seat in the company of wealth
Jọ́ládé Jọ́lá Let wealth come
Jọláadé Jọlá/Adé Enjoy the wealth of crown
Jọ́láyẹmi Jọla/Yẹmi Let wealth suit me
Káriọlá Kári The wealth got round
Kayinsọla Káyin Drop honey in to wealth
Kẹ́misọ́lá Kẹ́mi Pet me into wealth
Kọ́lápọ̀ Kọ́lá Bring wealth together
Kọ́láwọlé Kọ́lá Bring wealth home
Mobọ́láji Bọ́láji I woke up with wealth
Monisọ́lá Moni There is an addition to my wealth
Mosúnmọ́lá Mosún I got closer to wealth
Moyọ̀sádé Moyọ̀ I rejoice into crown
Moyọ̀sọ́lá Moyọ̀ I rejoice into wealth
Ninisọ́lá Nini Having an addition to wealth

Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-07-04 23:41:51. Republished by Blog Post Promoter