“Ìwà bi Ọlọrun pẹ̀lú Ìtẹ́lọ́rùn, Èrè nla ni” – “Godliness with Contentment, is great Gain”

 Ìtẹ́lọ́rùn - Contentment. Courtesy: @theyorubablog

Ìtẹ́lọ́rùn – Contentment. Courtesy: @theyorubablog

Bi kò bá si ìtẹ́lọ́rùn, kò si ohun ti èniyàn ni ti ó tó.  À i ni ìtẹ́lọ́rùn ló nfa iwà burúkú bi, olè̀ jijà, àgbèrè, ojúkòkòrò, irà-kurà, ijẹ-kújẹ, ìpànìyàn, gbi gbé oògùn olóró àti àwọn àlébù yoku.  Kò si owó ti ẹni ti kò ni ìtẹ́lọ́rùn lè ni, ki ó tó.

Yorùbá ni “Isà òkú ki i yó”, bẹ́ ẹ̀ ló ri fún a lai ni ìtẹ́lọ́rùn, nitori ojoojúmọ́ ni ohun tuntun njade, pàtàki ni ayé oriṣiriṣi ẹ̀rọ igbàlódé àti ẹ̀rọ ayélujára yi.  Fún àpẹrẹ, oriṣiriṣi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ló wà, ti wọn nṣe jade ni ọdọdún, àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ igbàlódé owó iyebiye.  Pẹ̀lú ìṣẹ́ ti ó pọ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú, ọkọ̀ ilẹ́ kò tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú àti Olóri-Ìjọ mọ, ọkọ̀-òfúrufú bi ó ti wọ́n tó, ni wọn nkó jọ.  Nitori eyi, kò si owó ti ó lè tó fún ẹni ti ó bá fẹ́ràn ohun ayé.

Ẹ̀kọ nla ni lati kọ́ ọmọ ni ìtẹ́lọ́rùn lati kékeré.  Ẹni ti ó bá ni ìtẹ́lọ́rùn, ló ni ohun gbogbo, nitori ko ni wo aago aláago ṣiṣẹ́, á lè lo ohun ti ó bá ni pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn.

Pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, “Ohun ti kò tó loni mbọ̀ wá ṣẹ́kù ni ọ̀la” bi èniyàn bá lè farabalẹ̀.

ENGLISH TRANSLATION

If there is no contentment, nothing can ever be enough.  Lack of contentment is the root cause of many character disorders, such as stealing, adultery, greed, compulsive shopping, gluttony, killings, drug peddling and other vices.  No amount of money is ever enough for someone who lacks contentment.According to Yoruba adage, “The Grave is never full”, so it is for the person that lacks contentment, because there are always new invention on a daily basis particularly in this modern Technological and Computer age.  For example, there are various designs of pleasure cars that are rolled out yearly and many expensive mobile phones.  In spite of so much poverty in Africa, many Politicians and Church Leaders are no longer content with expensive cars, but with Aircrafts despite its cost, are being acquired.  As a result, no amount of wealth can ever be enough for those who love worldly things.

It is a great education to train children contentment.  A contented person has everything, because such a person cannot be pushed by peer pressure and can manage whatever he/she has.

With contentment “What is not enough now will be excess tomorrow”, if one can be patient or calm down.

Share Button

Originally posted 2015-05-22 16:00:00. Republished by Blog Post Promoter

1 thought on ““Ìwà bi Ọlọrun pẹ̀lú Ìtẹ́lọ́rùn, Èrè nla ni” – “Godliness with Contentment, is great Gain”

  1. Victor Williamson

    Ìwà rere nípasẹ̀ ìtẹ́lọ́rùn ni èrè gan an ni fún ọmọ ìlú dúdú. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. A dúpẹ́ fún ọ̀rọ̀ ìwàásù yìí.

    Reply

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.