Ìkà ò jẹ́ ṣe ọmọ ẹ bẹ́ẹ̀ – Gbi gba wèrè mọ ẹ̀sìn Aláwọ̀-dúdú: The wicked always protect their own – Religious madness in Africa

Libya migrants: Muslim refugees arrested in Italy for throwing Christians into sea after fight

Libya migrants: Muslim refugees arrested in Italy for throwing Christians into sea after fight

Ni ọjọ́ kẹrin-din-lógún, oṣ̀u kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdógún, ọwọ́ Ọlọpa Italy tẹ ọkunrin mẹ̃dogun ti ó ju àwọn Ìgbàgbọ́ mejila si odò nitori ẹ̀sìn lati inú ọkọ̀ ojú agbami ti o nko Aláwọ̀-dúdú ti ó nsa fún ogun àti iṣẹ lo si Òkè-òkun/Ilú-Òyinbò.

Ni gbogbo ọ̀nà ni Aláwọ̀-dúdú fi gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Lára gbi gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn ni Àlùfã fi ni ki àwọn ọmọ ijọ bẹ̀rẹ̀ si jẹ koríko ti ọmọ rẹ kò lè jẹ, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ijọ ti ó jẹ koríko ló gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Ọmọ ijọ ti kò le bọ ara rẹ tàbi bọ ọmọ, ti ó nda ida-mẹwa nigbati Olóri Ijọ nfi owó yi gun ọkọ̀ òfúrufú fi han pé ọ̀pọ̀ ti gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Aládurà ti ó nri iran ti kò ri tara rẹ gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.

A screen capture from a Boko Haram video purporting to show the kidnapped girls

‘The Chibok girls are never being freed,’ says Boko Haram leader

Ẹlẹ́sin Mùsùlùmi ti ó npa ẹlòmíràn ni orúkọ ẹ̀sìn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Eyi ti ó ni èèwọ̀ ni iwé kika fún ẹ̀sìn ohun “Boko Haram” ti wọn fi nba ilé iwé jẹ, ji àwọn obinrin kò kúrò ni ilé iwé, fihàn pé wọn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Ọjọ́ kẹrinla oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdógún ló pé ọdún kan ti ẹgbẹ́ burúkú “Boko Haram” ti ko igba-le-mọkandinlógún obinrin kúrò ni ilé-iwè ni Chibok.  Lèmọ́mù rán ọmọ tirẹ̀ lọ si ilé-iwé, irú àwọn ọmọ Lèmọ́mù ti ó ka iwé ni ó nṣe Òṣèlú tàbi jẹ ọ̀gá ni iṣẹ́ Ìjọba.

Kò si Òṣèlú Aláwọ̀-dúdú ti kò sọ pé ohun jẹ Onígbàgbọ́ tàbi Mùsùlùmi ṣùgbọ́n eyi kò ni ki wọn ma ja ilú ni olè.  Ìfẹ́ agbára ki jẹ ki wọn fẹ gbe ipò silẹ̀ nitori eyi wọn á fi ẹ̀sìn da ilú rú.  Eleyi ló fa ogun ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú.

Kàkà ki Aláwọ̀-dúdú yẹ ara wọn wò, gbogbo ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì fẹ́ kó kúrò ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú lọ si Òkè-òkun/ilú òyinbó.  Bi gbogbo ará ilú Aláwọ̀-dúdú bá kó lọ si Òkè-òkun/ilú òyinbó pẹ̀lú bi wọn ṣe gba were mo esin, wọn á ba ibẹ̀ jẹ́.  “Ọjọ́ ti wèrè bá ti mọ̀ pé wèrè ni ohun ni iwòsàn bẹ̀rẹ̀”, bi Aláwọ̀-dúdú  kò bá mọ̀ pé wọn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn, kò lè si àtúnṣe ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú.

Ìkà kò jẹ́ ṣe ọmọ rẹ bẹ́ ẹ̀, ọmọ Olóri Ìjọ, Lèmọ́mù àti àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú kò si ninú àwọn ti ó nkú si odò nitori àti lọ si Òkè-òkun ni tipá-tipá.   Ìwà ikà àti ijà nitori ẹ̀sìn kò mú ọgbọ́n dáni.

ENGLISH TRANSLATION

On the fourteenth of April Twenty-fifteen, the Italian Police arrested fifteen men that threw over board twelve Christians from the ship bringing Africans who were fleeing from war and poverty to Abroad/Europe.

African’s religious madness are reflected in every way.  Evidence of religious madness can be seen in the incidence of the Pastor who asked his Church members to eat grass that he could not ask his children to eat, but the members who ate grass without question can be said to be religiously mad.  The poor folks who are unable to feed themselves or their children and yet contribute tithe for a Pastor using the tithe to ride a jet shows religious madness.  Acclaimed Prophets who keep prophesying without seeing vision of evil occurrence in his/her immediate environ can be said to be religious madness.

Other evidence of religious madness can be traced to Muslim killing others in the name of religion.  Those who said “Western Education is forbidden” “Boko Haram” that led them to destroying Schools, abducting School girls are simply mad.  On the fourteen of April, Twenty-fifteen, it became one year that the terrorist group “Boko Haram” abducted the two hundred and nineteen girls from School in Chibok.  Imam and prominent Muslims send their children to School, such children later become Politicians or big bosses in Government Service.

There is no African Politician that is not claiming to be Christian or Muslim but this never deterred them from stealing public funds.  Love of power make them to cling to positions using religion to sow discord among the people.  This is one of the main causes of war in many of the African countries.

Instead of Africans re-examining their situation, both the rich and the poor wants to migrate Abroad/Europe.  If all Africans migrate Abroad/Europe with their religious madness, they will end destroying there.  Yoruba adage said “Healing can only begin When a mad person realize his/her true condition”, if African fail to realize the havoc caused by religious madness, there can be no restoration.

The wicked will never treat their children wickedly, children of Christians and Muslim leaders and Politicians are not among the migrants dying on the sea as a result of migrating to Europe at all cost.  Wickedness and war in the name of religion is not sensible.

Share Button

Originally posted 2015-04-18 00:30:26. Republished by Blog Post Promoter

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.