Category Archives: Yoruba Folklore

“Ìtàn bi Ìjàpá ti fa Àkóbá fún Ọ̀bọ: Ẹ Ṣọ́ra fún Ọ̀rẹ́ Burúkú” – “The Story of how the Tortoise caused the Monkey an unprovoked trouble: Be careful with a bad Friend”

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ itàn Yorùbá, Ìjàpá jẹ ọ̀lẹ, òbùrẹ́wà, kò tóbi tó àwọn ẹranko yoku, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n àrékérekè ti ó fi ngbé ilé ayé.

Ò̀we Yorùbá sọ wi pé, “Iwà jọ iwà, ni ọ̀rẹ́ jọ ọ̀rẹ́”, ṣùgbọ́n ninú itàn yi, iwà Ìjàpá àti Ọ̀bọ kò jọra.  Ìjàpá  pẹ̀lú Ọ̀bọ di ọ̀rẹ́ nitori wọn jọ ngbé àdúgbò.  Gbogbo ẹranko yoku mọ̀ wi pé iwà wọn kò jọra nitori eyi, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn irú ọ̀rẹ́ ti wọn bára ṣe.

Ọgbọ́n burúkú kó wọn Ìjàpá, ni ọjọ́ kan ó bẹ̀rẹ̀ si ṣe àdúrà lojiji pé “Àkóbá , àdábá, Ọlọrun ma jẹ ká ri”, Ọ̀bọ kò ṣe “Àmin àdúrà” nitori ó mọ̀ wi pé kò si ẹni ti ó lè ṣe àkóbá fún Ìjàpá, à fi ti ó bá ṣe àkóbá fún elòmiràn.  Inú bi Ìjàpá, ó ka iwà Ọ̀bọ yi si à ri fin, ó pinu lati kọ lọ́gbọ́n pé ọgbọ́n wa ninú ki enia mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà.

Ìjàpá ṣe àkàrà ti ó fi oyin din, o di sinú ewé, ó gbe tọ Ẹkùn lọ.  Ki Ẹkùn tó bèrè ohun ti Ìjàpá nwa lo ti gbo oorun didun ohun ti Ìjàpá Ijapa gbe wa.  Ìjàpá jẹ́ ki Ẹkùn játọ́ titi kó tó fún ni àkàrà olóyin jẹ. Àkàrà olóyin dùn mọ́ Ẹkùn, ó ṣe iwadi bi òhun ti lè tún ri irú rẹ.  Ìjàpá ni àṣiri ni pé Ọ̀bọ ma nṣu di dùn, lára igbẹ́ rẹ ni òhun bù wá fún Ẹkùn.  Ó ni ki Ẹkùn fi ọgbọ́n tan Ọ̀bọ, ki ó si gba ni ikùn diẹ ki ó lè ṣu igbẹ́ aládùn fun.  Ẹkùn kò kọ́kọ́ gbàgbọ́, ó ni ọjọ́ ti òhun ti njẹ ẹran oriṣiriṣi, kò si ẹranko ti inú rẹ dùn bi eyi ti Ìjàpá gbé wá.  Ìjàpá ni ọ̀rẹ òhun kò fẹ́ ki ẹni kan mọ àṣiri yi.  Ẹkùn gbàgbọ́, nitori ó mọ̀ wi pé ọ̀rẹ́ gidi ni Ìjàpá àti Ọ̀bọ.

Ẹkùn gba ikùn Ọ̀bọ - Leopard dealt the Monkey blows.

Ẹkùn gba ikùn Ọ̀bọ – Leopard dealt the Monkey blows.

Ẹkùn lúgọ de Ọ̀bọ, ó fi ọgbọ́n tan ki ó lè sún mọ́ òhun.  Gẹ́rẹ́ ti Ọ̀bọ sún mọ́ Ẹkùn, o fã lati gba ikùn rẹ gẹ́gẹ́ bi Ìjàpá ti sọ, ki ó lè ṣu di dùn fún òhun.  Ó gbá ikun Ọ̀bọ titi ó fi ya igbẹ́ gbi gbóná ki ó tó tu silẹ̀.  Gẹ́rẹ́ ti Ẹkùn tu Ọ̀bọ silẹ̀, ó lo agbára diẹ ti ó kù lati sáré gun ori igi lọ lati gba ara lowo iku ojiji.  Ẹkùn tọ́ igbẹ́ Ọ̀bọ wò, inú rẹ bàjẹ́, ojú ti i pé òhun gba ọ̀rọ̀ Ìjàpá gbọ.  Lai pẹ, Ìjàpá ni Ọ̀bọ kọ́kọ́ ri, ó ṣe àlàyé fún ọ̀rẹ́ rẹ ohun ti ojú rẹ ri lọ́wọ́ Ẹkùn lai funra pé Ìjàpá ló fa àkóbá yi fún òhun.  Ìjàpá ṣe ojú àánú, ṣùgbọ́n ó padà ṣe àdúrà ti ó gbà ni ọjọ́ ti Obo kò ṣe “Amin”, pé ọgbọ́n wà ninú ki èniyàn mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà.  Kia ni Ọ̀bọ bẹ̀rẹ̀ si ṣe “Àmin” lai dúró.  Idi ni yi ti Ọ̀bọ fi bẹ̀rẹ̀ si kólòlò ti ó ndún bi “Àmin” titi di ọjọ́ òni.

Ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, bi èniyàn bá mbá ọ̀rẹ́ ọlọ́gbọ́n burúkú rin, ki ó mã funra tàbi ki ó yẹra, ki o ma ba ri àkóbá.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-16 22:39:59. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn ti a o kà loni dá lórí ìdí ti ọmọ Ẹkùn fi di Ológbò – The Yoruba story being read is on “how a Tiger Cub became a Cat”

Yorùbá ma npa ìtàn lati fi ṣe à ri kọ́gbọ́n tàbi fún ìkìlọ̀.  Ẹ ṣọ́ra lati fi ìbẹ̀rù àti ojo bẹ̀rẹ̀ ọdún nitori a ma a géni kúrú. Lára ẹ̀kọ́ ti a lè ri fi kọ́ ọgbọ́n ni ìtàn ti a ka yi ni wi pé, onikálukú ni Ọlọrun fún ni ẹ̀bùn àti àyè ti rẹ̀ ni ayé.  Ohun ti ó dára ni ìṣọ̀kan, ẹ̀kọ́ wa lati kọ́ lára bi ẹranko ti ó ni agbára ṣe mba ara wọ́n gbé, ó dára ki a gba ìkìlọ̀ àgbà tàbi ẹni ti ó bá ṣe nkan ṣáájú àti pé ìjayà tàbi ìbẹ̀rù lè gé ènìà kúrú bi o ti sọ ọmọ Ẹkùn di Ológbò.

Ẹ ka ìtàn yi ni èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ojú ewé Yorùbá lóri ayélujára ti a kọ ni ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún, oṣù kẹta, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n.

ENGLISH TRANSLATION

In Yoruba Culture stories are told to learn from example or to warn.  Be careful on stepping into the New Year with fear, because fear reduces one’s potential.  Some of the lessons that can be Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-01-19 00:47:17. Republished by Blog Post Promoter

Ajá dúró dèmί lọna, fẹrẹ kun fẹ 2ce
Bί ὸ bá dúró dèmί lọna fẹrẹ kun fẹ
Makékéké Olóko á gbọ fẹrẹ kun fẹ
Á gbọ á gbéwa dè, fẹrẹ kun fẹ
Á gbéwa dè, á gbàwá nίṣu fẹrẹ kun fẹ
Ajá dúró dèmί lọna, fẹrẹ kun fẹ 2ce


You can also download a recital by right clicking this link: Ajá dúró dèmί lọna

“Àjàpá fẹ́ kó bá Ajá – Kàkà ki eku májẹ sèsé, á fi ṣe àwàdànu” – “Tortoise tried to implicate the Dog – The rat, even if it can’t eat the grain, would rather waste it”

Ni ayé atijọ, ìyàn mú ni ìlú àwọn ẹranko gidigidi, ti àwọn ẹranko fi ńwá oúnjẹ kiri.  Iṣu je oúnjẹ gidi ni ilẹ Yorὺbá.  Àjàpá àti Ajá gbimọ̀ pọ, lati lọ si oko olóko lati lọ ji iṣu.

Àjàpá jẹ ara ẹranko afàyà fà, ti ko le sáré bi ti Ajá ṣùgbọ́n o lọgbọn gidigidi.  Nίgbàtί Àjàpá́ àti Ajá ti jίṣu ko tán, ajá nsáré tete lọ, ki olóko má ba kawọn mọ.

Yorὺbá ni “Kàkà ki eku májẹ sèsé, á fi ṣe àwàdànu”. Àjàpá́ ri wipe ὸhun o le bá Ajá sáré, ó bá ti orin ikilọ bẹnu kί Ajá ba le dúró de ὸhun ni tipátipá.   Bί Ajá ko ba dúró, nitotọ olóko á gbọ igbe Àjàpá́, yio si fa àkóbá fún Ajá.  Àjàpá́ ko fẹ dá nìkan pàdánú nίtorί olóko á gba iṣu ti ohun jί kó, á sì fi ìyà jẹ ohun.

Titi di ọjọ́ òni, àwọn èniyàn ti o nhu iwà bi Àjàpá pọ̀, ni pàtàki àwọn Òsèlú. .  Ikan ninú ẹ̀kọ́ itàn àdáyébá yi ni, lati ṣe ikilọ fún àwọn ti o nṣe ọ̀tẹ̀, ti o nhu iwà ibàjẹ́ tàbi rú òfin pé ki wọn jáwọ́ ninú iwà burúkú.  Ìtàn yί  tún dára lati gba èniyàn ni iyànjú wίpé ki a má ṣe nkan àṣίrί si ọwọ́ ẹnikẹni pàtàkì ohun ti ko tọ́ tàbί ti ó lὸdì si ὸfin.  Yorὺbà ni “Mo ṣé tàn lówà, kὸ sί mo ṣégbé” bó pẹ bó yá, àṣίrί á tú.

̀yin ọmọ Yorὺbá nίlé lóko, ẹ jẹ ká hὺwà otitọ kί á sì pa ὸfin mọ, kί a má ba rί àkóbá pàtàkì ọmọ Yorὺbá nί  Òkèokun/Ìlúὸyìnbó.

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-14 10:15:01. Republished by Blog Post Promoter

Àjàpá àti Ọmọdé Mẹta – “Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ló́ nmú ọ̀ràn bá ẹ̀rẹ̀kẹ́” – The Tortoise and the three playful children “A mouth that will not stay shut, the lips that will not stay closed, invites trouble for the cheek”

Ni abúlé Yorùbá nigbati ko ti si ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsì tabi ẹ̀rọ amú-òhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ ayélujára, àwọn ọmọdé má nkó ara jọ lati ṣe eré lẹhin iṣẹ́ oojọ Bàbá àti Ìyá wọn.  Pataki, ni igba ọ̀gbẹlẹ̀ nigbati iṣẹ́ oko din kù.

Ọmọdé Mẹta - 3 young boys playing.  Courtesy: @theyorubablog

Ọmọdé Mẹta – 3 young boys playing. Courtesy: @theyorubablog

Àwọn ọmọdé kunrin mẹta bẹ̀rẹ̀ si ṣe eré ìdárayá leti òkun lai bikità ohun ti ó nlọ ni àyíká.  Ọmọ kini lérí pé ohun lè gun igi ọ̀pẹ pẹ̀lu ọwọ́ lásá̀n, ekeji ni ohun lè wẹ òkun yi já, ẹni kẹta ni ohun lè ta ọfà si ọ̀run.  Àjàpá gbọ́ gbogbo ìlérí àwọn mẹta yi ṣe, ó gbé ìròyìn lọ fún Ọba, pé ohun ti ri àwọn ti ó lè ṣe nkan ti ẹni kan kò ṣerí.  Ọba àti àgbà ìlú kò fẹ́ gba ohun ti Àjàpá wi gbọ́ nitori ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n o ni ki Ọba ṣe ohun ti ó bá fẹ́ fún ohun ti ìròyìn ti ohun mú wá kò bá ṣẹ.

Ọba ránṣẹ́ pé àwọn ọmọdé kunrin mẹta yi, pé ki wọn wa ṣe ohun ti wọn ṣèlérí pé wọn lè ṣe.  Yorùbá ni “Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ló́ nmú ọ̀ràn bá ẹ̀rẹ̀kẹ́”.  Ìbẹ̀rù ba àwọn ọmọ yi, ẹbí wọn bẹ Ọba pe eré ọmọdé lásán ni àwọn ọmọ yi fi sọ gbogbo ohun ti wọn sọ, ṣùgbọ́n ẹ̀pa ò bóró mọ́ gbogbo ará ìlú (àti Àjàpá) ti pé jọ lati wòran.  Àwọn ọmọde mẹta yi bẹ̀rẹ̀ si kọ orin arò bayi:

 

Ọmọdé mẹ́ta nṣère

Éré o, érè ayọ̀ 2ce

Ọ̀kán lóhun yó gọ̀p

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀gọ̀pẹ, ọ̀gọ̀pẹ, ọ̀gọ̀p

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀kán lóhun yó wẹ̀kun

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀wẹ̀kun, ọ̀wẹ̀kun, ọ̀wẹ̀kun

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀kán lóhun ó tafà sọ́run,

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀tàfa, ọ̀tàfa, ọ̀tàfa

Éré o, érè ayọ̀.

Èyi ti ó ni ohun lè gun ọ̀pẹ, dé ìdí ọ̀pẹ pẹ̀lú ẹkún.  O gun lẹ̃ kini, ó ṣubú, o gun lẹ̃ keji kọjá ibi tó dé ni àkọ́kọ́ ki ó tó ṣubú.  Èyi jẹ ki àwọn ará ìlú bẹ̀rẹ̀ si pàtẹ́wọ́ lati ki láyà, ó bá mú ọ̀pẹ gùn ni ẹ̃kẹta, ó́ gun dé orí.  Ariwo sọ, inú ará ìlú dùn.  Nigbati ọmọdé keji ti o ni ohun lè wẹ́ òkun ja, gbọ́ ariwo ìdùn nú yi, eleyi ki láyà.  Bi ti ẹni àkọ́kọ́, ọmọdé keji ti ó ni ohun lè wẹ òkun já, o wẹ dé odi keji, nibiti wọn ti fi ijó àti ayọ̀ pàdé rẹ.  Eleyi ló fún ọmọdé kẹta ni ìgboiyà pe ohun na lè ṣe ohun ti ohun ti ṣe ìlérí rẹ.  Ó ta ọfà lẹ̃ kini, ọfà na, kò rin jinà ki o to wálẹ̀.  O tã lẹ̃ keji, ọfà yi lọ bi ẹni pé kòní padà̀ si ilẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún wálẹ̀ .  Ni igbà kẹta ọfà na lọ sókè ọ̀run lai padà.  Ariwo sọ, ṣùgbọ́n ìtìjú bo Àjàpá. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-09-20 22:16:26. Republished by Blog Post Promoter

Ààntéré ọmọ Òrìṣà-Omi – “Ọmọ o láyọ̀lé, ẹni ọmọ sin lo bimọ”: Aantere – The River goddess child “Children are not to be rejoiced over, only those whose children bury them really have children”.

Yorùbá ka ọmọ si ọlá àti iyì ti yio tọ́jú ìyá àti bàbá lọ́jọ́ alẹ́.  Eyi han ni orúkọ ti Yorùbá nsọ ọmọ bi: Ọmọlọlá, Ọmọniyi, Ọmọlẹ̀yẹ, Ọmọ́yẹmi, Ọlọ́mọ́là, Ọlọ́mọlólayé, Ọmọdunni, Ọmọwunmi, Ọmọgbemi, Ọmọ́dára àti bẹ̃bẹ̃ lọ.  A o tun ṣe akiyesi ni àṣà Yorùbá pe bi obinrin ba wọ ilé ọkọ, wọn ki pe ni orúkọ ti ìyá ati bàbá sọ, wọn a fun ni orúkọ ni ilé ọkọ.  Nigbati ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé wọn a pe ni “Ìyàwó” ṣùgbọ́n bi ó bá ti bímọ a di “Ìyá orúkọ àkọ́bí”, bi ó bá bi ibeji tabi ibẹta a di “Ìyá Ibeji tàbi Ìyá Ibẹta”.  Bàbá ọmọ a di “Bàbá orúkọ ọmọ àkọ̀bí, Bàbá Ibeji tàbi Bàbá Ìbẹta”.  Nitori idi eyi, ìgbéyàwó ti kò bá si ọmọ ma nfa irònú púpọ̀.

Ni abúlé kan ni aye atijọ, ọkọ ati ìyàwó yi kò bímọ fún ọpọlọpọ ọdún lẹhin ìgbéyàwó.  Nitori àti bímọ, wọn lọ si ilé Aláwo, wọn lọ si ilé oníṣègùn lati ṣe aajo, ṣùgbọ́n wọn o ri ọmọ bi.  Aladugbo wọn gbà wọn niyanju ki wọn lọ si ọ̀dọ̀ Olóri-awo ni ìlú keji.  Ọkọ àti ìyàwó tọ Olóri-awo yi lọ lati wa idi ohun ti wọn lè ṣe lati bímọ.  Olóri-awo ṣe iwadi lọ́dọ̀ Ifa pẹ̀lú ọ̀pẹ̀lẹ̀ rẹ, o ṣe àlàyé pe ko si ọmọ mọ lọdọ Òrìṣà ṣùgbọ́n nigbati ẹ̀bẹ̀ pọ, o ni ọmọ kan lo ku lọdọ Òrìṣà-Omi, ṣùgbọ́n ti ohun bá gba ọmọ yi fún wọn kò ni bá wọn kalẹ́, nitori ti o ba lọ si odò ki ó tó bi ọmọ ni ilé ọkọ yio kú, Òrìṣà-Omi á gba ọmọ rẹ padà.  Ọkọ àti Ìyàwó ni awọn a gbã bẹ.

Ààntére lọ fọ abọ́ lódò - Aantere went to the River to do dishes.  Courtesy: @theyorubablog

Ààntére lọ fọ abọ́ lódò – Aantere went to the River to do dishes. Courtesy: @theyorubablog

Ìyàwó lóyún, ó bi obinrin, wọn sọ ni “Ààntéré” eyi ti ó tumọ si “Ọmọ Omi”.  Gbogbo ẹbi àti ará bá wọn yọ̀ ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ.  Ni ọjọ kan, Ààntéré bẹ awọn òbí rẹ pé ohun fẹ́ sáré lọ fọ abọ́, awọn òbí rẹ kọ.  Nigbati ẹ̀bẹ̀ pọ wọn gbà nitori o ti dàgbà tó lati wọ ilé-ọkọ, wọn ti gbàgbé ewọ ti Olóri-awo sọ fún wọn pe, o ni lati wọ ile ọkọ ki o to bímọ.  Ààntéré dé odò, Òrìṣà-omi, ri ọmọ rẹ, o fi iji nla fa Ààntéré wọ inú omi lai padà.

Ìyá àti Bàbá Ààntéré, reti ki ó padà lati odò ṣùgbọ́n kò dé, wọn ké dé ilé Ọba, Ọba pàṣẹ ki ọmọdé àti àgbà ìlú wa Ààntéré lọ.  Nigba ti wọn dé idi odò, wọn bẹrẹ si gbọ orin ti Ààntéré nkọ, ṣùgbọ́n wọn ò ri.

Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-10-11 20:24:26. Republished by Blog Post Promoter

Àjàpá rẹ Erin sílẹ̀ – “Ìjàlọ ò lè jà, ó lè bọ́ ṣòkòtò ni idi òmìrán”: The Tortoise humbled the Elephant – “Soldier ant cannot fight, but can cause the giant to remove pant”.

Erin jẹ ẹranko ti Ọlọrun da lọ́lá pẹlu titobi rẹ ninu igbo.  Yorùbá ni “Koríko ti Erin bá ti tẹ̀, àtẹ̀gbé ni láyé”, oko ti Erin bá wọ̀, olóko bẹ wọ igbèsè tori ibajẹ ti o ma ṣẹlẹ̀ si irú oko bẹ.  Gbogbo ẹranko bọ̀wọ̀ fún Erin, nitori Kìnìún ọlọ́là ijù kò lè pa Erin.

Bi Erin ti tóbi tó, ni ó gọ̀ tó.  Ni ọjọ́ kan, gbogbo ẹranko pe ìpàdé lati pari ìjà fún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Kìnìún.  Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ni bi ohun ba pa ẹran, Kìnìún a fi ògbójú gba ẹran yi jẹ.  Kàkà ki Erin da ẹjọ́ pẹ̀lú òye, ṣe ló tún dá kun.  Ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga ni àwùjọ yi bi awọn ẹranko yoku ninu.  O bi Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ninu to bẹ gẹ ti kò lè fọhùn.  Àjàpá nikan lo dide lati fún Erin ni èsì ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ẹranko yoku bú si ẹ̀rín nitori wọn fi ojú di Àjàpá.  Dipo ki Àjàpá panumọ́, ó pe erin níjà.

Ni ọjọ́ ìjà, Erin kò múra nitori ó mọ̀ pé bi Àjàpá ti kéré tó, bi ohun bá gbé ẹsẹ̀ le, ọ̀run lèrọ̀. Àjàpa mọ̀ pé ohun ko ni agbára, nitori eyi, ó dá ọgbọ́n ti yio fi bá Erin jà lai di èrò ọ̀run.  Àjàpá ti pèsè, agbè mẹta pẹlu ìgbẹ́, osùn àti ẹfun ti yio dà lé Erin lóri lati dójú ti.  Ó tọ́jú awọn agbè yi si ori igi nitosi ibi  ti wọn ti fẹ́ jà, ó mọ̀ pé pẹ̀lú ibinu erin á jà dé idi ibi ti yio dà le lori.

Awọn ẹranko péjọ lati wòran ijà lãrin Àjàpá àti Erin.  Àjàpá mọ̀ pe bi erin bá subú kò lè dide, nigbati ti ijà bẹ̀rẹ̀, ẹhin ni Àjàpá wà ti o ti nsọ òkò ọ̀rọ̀ si erin lati dá inú bi.  Pẹ̀lú ibinú, ki ó tó yípadà dé ibi ti Àjàpá wa, Àjàpá a ti kósi lábẹ́, eleyi dá awọn ẹranko lára yá.

Yorùbá ni “Bi ìyà nla ba gbeni ṣánlẹ̀, kékeré á gorí ẹni” ni ikẹhin, Àjàpá bori erin pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ẹranko gbé Àjàpá sókè pẹ̀lú ìdùnnú gun ori ibi ti erin wó si.

Ìtàn Yorùbá yi fihan pé kò si ẹni ti a lè fi ojú di.  Ti a bá fẹ́ ka ìtàn yi ni ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni èdè Gẹẹsi, ẹ ṣe àyẹ̀wò rẹ ninu iwé “Yoruba Trickster Tales” ti Oyekan Owomoyela kọ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-10-25 17:02:09. Republished by Blog Post Promoter

Àjàpá sọ Ẹlẹ́dẹ̀ di ọ̀bùn – “Alágbára má mèrò; baba ọ̀le; Ọgbọ́n ju agbára” – The Tortoise turned the Pig to the filthy one – One who has strength but is thoughtless is the father figure of laziness –wisdom is mightier than strength

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Àlébù ki ṣe ẹ̀gàn tàbi agọ̀; ṣùgbọ́n, ẹ̀gàn àti agọ̀ ni fún ẹni ti ojú rẹ fọ́ si àlébù ara rẹ”.  Irú ẹni bẹ̃, kò lè ri àtúnṣe tàbi sọ àlèbú yi di ohun ini.  Ninú ìtàn bi Àjàpá ti sọ Ẹlẹ́dẹ̀ di ọ̀bùn ti a mọ̀ si titi di oni, Àjàpá jẹ́ ẹranko ti kò lè yára rin tàbi ni agbára iṣẹ́ àti ṣe lówó, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n lati bo àlébù rẹ.

Yorùbá ni “Alágbára má mèrò; baba ọ̀le; Ọgbọ́n ju agbára”.  Àjàpá́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹwẹ, nigbati Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ alágbá̀ra ti kò mèrò.  Kò si ohun ti Àjàpá lè ṣe lai ni idi tàbi ọgbọ́n àrékérekè, nitori eyi, ó sọ ara rẹ di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dẹ̀ nitori gbogbo ẹranko yoku ti já ọgbọ́n rẹ.  Ẹlẹ́dẹ̀ kò fi ọgbọ́n wá idi irú ọ̀rẹ́ ti Àjàpá jẹ́.  Laipẹ, Àjàpá lọ yá owó lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lu àdéhùn pe ohun yio san owó na padà ni ọjọ́ ti ohun dá.  Ẹlẹ́dẹ̀ rò pé ọ̀rẹ́ ju owó lọ, ó gbà lati yá Àjàpá lówó nitori àdéhùn rẹ.

Nigbati ọjọ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ reti titi ki ó wá san owó ti ó yá, ṣù̀gbọn Àjàpá kò kúrò ni ilé rẹ nitori ó mọ̀ pé ohun kò ni owó́ lati san.  Àjàpá fi ohun pẹ̀lẹ́ ṣe àlàyé pé bi ohun ti fẹ́ ma kó owó lọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ ni olè dá ohun lọ́nà, ti wọn gba gbogbo owó lọ.  Inú Ẹlẹ́dẹ̀ kò dùn nitori kò gba iṣẹ̀lẹ̀ yi gbọ́, ṣùgbọ́n ó gba nigbati Àjàpá tún dá ọjọ́ miran lati san owó na.  Bi Ẹlẹ́dẹ̀ ti kúrò ló bá aya rẹ “Yáníbo” dìmọ̀pọ̀ bi ohun kò ti ni san owó padà.  Ó ni bi ọjọ́ bá pé, bi Yáníbo bá ti gbọ́ ìró Ẹlẹ́dẹ̀, kó yi ohun padà, ki ó bẹrẹ si lọ ẹ̀gúsí ni àyà ohun lai dúró bi Ẹlẹ́dẹ̀ bá wọlé bèrè ohun.

Àjàpa ninu ẹrọ̀fọ̀ ti Ẹlẹ́dẹ̀ ju si - The Tortoise thrown by the Pig into the swamp.  Courtesy: @theyorubablog

Àjàpa ninu ẹrọ̀fọ̀ ti Ẹlẹ́dẹ̀ ju si – The Tortoise thrown by the Pig into the swamp. Courtesy: @theyorubablog

Ni ọjọ́ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ dé lati gba owó rẹ, Yáníbo ṣe bi ọkọ rẹ ti wi.  Ẹlẹ́dẹ̀ fi ibinu gbé ọlọ àti ẹ̀gúsí sọnù si ẹrọ̀fọ̀ ti ó wá ni ìtòsí lai mọ̀ pé Àjàpá ni ọlọ yi.  Yáníbo fi igbe ta titi ọkọ rẹ fi wọlé.  Àjàpá yọ ara rẹ̀ kúrò ninú ẹrọ̀fọ̀, ó nu ara rẹ̀, ó ṣe bi ẹni pé ohun kò ri Ẹlẹ́dẹ̀ nigbati ó délé.  Ó bèrè ohun ti ó fa igbe ti Yáníbo ńké.  Yáníbo ṣe àlàyé.

Ẹlẹ́dẹ̀i fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ - The Tortoise prout in the swamp.  Courtesy: @theyorubablog

Ẹlẹ́dẹ̀i fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ – The Tortoise prout in the swamp. Courtesy: @theyorubablog

 

 

Yorùbá ni “Ọ̀bùn ri ikú ọkọ tìrọ̀ mọ́, ó ni ọjọ́ ti ọkọ ohun ti kú ohun ò wẹ̀”.  Àjàpá ri ohun ṣe àwá-wi, ó sọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ pé ọlọ ti ó gbé sọnù ṣe pataki fún idilé àwọn, nitori na ó ni lati wá ọlọ yi jade ki ohun tó lè san owó ti ohun yá.  Ẹlẹ́dẹ̀ wọnú ẹrọ̀fọ̀ lati wá ọlọ idile Àjàpá.  Lati igbà yi ni Ẹlẹ́dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ titi di ọjọ́ oni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-02-18 23:03:39. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn Yorùbá bi Àdán ti di “Ko ṣeku, kò ṣẹyẹ” – Yoruba Folklore on how the Bat became “Neither Rat nor Bird”

Adan - Flying Bat

Àdán fò lọ bá ẹyẹ – Bat flew to join the birds @theyorubablog

Ìtàn sọ wí pé eku ni àdán tẹ́lẹ̀ ki ìjà nla tó bẹ́ sílẹ̀ laarin eku àti ẹyẹ.  Àdán rò wípé àwọn ẹyẹ fẹ́ bori, nitorina o fo lati lọ darapọ̀ mọ́ ẹyẹ lati dojú ìjà kọ àwọn ẹbi rẹ eku.

Eku àti ẹyẹ bínú si àdàn nitori ìwà àgàbàgebè ti ó hu yi, wọ́n pinu lati parapọ̀ lati dojú ìjà kọ àdán.  Nitori ìdí èyí ni àdán ṣe bẹ̀rẹ̀ si sá pamọ́ lati fi òkùnkùn bora ni ọ̀sán fún eku àti ẹyẹ títí  di òní.

A lè fi ìtàn yi wé àwọn Òṣèlú tó nsa lati ẹgbẹ́ kan si ekeji nitori ipò̀ ati agbára lati kó owó ìlú jẹ.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, wọ́n ma “lé eku meji pa òfo” ni.  Ọkùnrin ti o ni ìyàwó kan, ni àlè sita ma fara pamọ́ lati lọ sí ọ̀dọ̀ obìnrin keji ti wọ́n rò wípé́ á fún wọn ní ìgbádùn.  Nígbàtí ìyàwó ilé bá gbọ́, wọn a pa òfo lọdọ ìyàwó ilé, wọn a tún tẹ́ lọ́dọ̀ àlè.

Ẹ̀kọ́ ìtàn yí ni wípé iyè meji kò dara, ọ̀dalẹ̀ ma mba ilẹ̀ lọ ni, nitorina, ojúkòkòrò kò lérè.

ENGLISH TRANSLATION

According to Yoruba folklore, the bat was once a rat, until a great fight broke out between the rats and the birds.  Sensing that birds might win the fight, some of the rats became bats, flying to join the birds against their rat kindred. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-09-11 09:20:28. Republished by Blog Post Promoter

Àìnítìjú lọba gbogbo Àlébù: Shamelessness is the king of all Vices

Gopher Tortoise

Ìjàpá ọkọ Yáníbo – Tortoise the husband of Yanibo

Gbogbo Ẹranko  - Group of Animals

Gbogbo Ẹranko – Group of Animals

Gbogbo Ẹranko (Ajá, Àmọ̀tẹ́kùn, Ẹkùn, Kìnìún, Ọ̀bọ, Akátá, Ológbò, Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, Ìjàpá/Àjàpá àti bẹ̃bẹ lọ) kó ara jọ lati gbèrò lórí àlébù tí wọ́n rí lára ìyàwó wọn.  Ajá ní ìyawó òhun nṣe àgbèrè, Ẹkùn ní ìyàwó òhun nṣe àfojúdi,  Ológbò ní ìyàwó òhun njale, Ọ̀bọ ní ìyàwó òhun lèjàjù àti bẹ̃bẹ lọ.  Àwọn Ẹranko yókù ṣe àkíyèsí wípé,

Àjàpá/Ìjàpá kàn mi orí ni lai sọ nkankan ju un!

Kìnìún wa bèrè lọ́wọ́ Ìjàpá wípé ṣe Yáníbo (ìyàwó Ìjàpá) kòní àlébù ni?  Àjàpá/Ìjàpá dìde ó wá fọhùn wípé gbogbo àlébù ti gbogbo wọn sọ nípa ìyàwó wọn kéré lára ti ìyàwó ohun nítorí “Yáníbo kò ní ìtìjú”.   Ẹni ti kó ni ìtìjú a jalè, a purọ́, a ṣe àgbèrè, a ṣe àfojúdi àti bẹ̃bẹ lọ.

Ni Ìlúọba, bi Òṣèlú bá ṣe ohun ìtìjú bi: àgbèrè, jalè, gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bi wọn bá ka mọ tàbí kó rò wípé aṣírí fẹ́ tú, á gbé ìwé sílẹ̀ pé òhun kò ṣe mọ nítorí ki ipò òhun má ba di ìdájọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n apàniyàn, olè, alágbèrè àti bẹ̃bẹ lọ., pọ nínú Òṣèlú Nigeria nítorí wọn kò ni ìtìjú.  Ipò Òṣèlú tiwọn fún wọn láyè lati ni àlébù àti lati tẹ ìdájọ́ mọ́lẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá tó ni “Àìnítìjú lọba gbogbo Àlébù” gba èrò lati ri wípé ará ìlú dìbò fún Afínjú Òṣèlú kí wọ́n lè ṣe àtúnṣe nkan  tí aláìnítìjú Òṣèlú ti bàjẹ́.

ENGLISH TRANSLATION

All the animals (Dog, Panther, Leopard, Lion, Monkey, Jackal, Cat, Donkey/Ass, Tortoise etc.) gathered together to discuss the vices they noticed in their wives.   Dog’s wife was said to be committing adultery, Leopard’s wife was insolent, Cat’s wife was stealing, while Monkey’s wife was quarrelsome etc.

All the animals noticed that there was no comment from the Tortoise other than nodding and sighing.  The Lion then asked what Yanibo (Tortoise’s wife) vice was?  The Tortoise rose up and said to the other animals that all the vices they have mentioned could not be compared with his wife’s only vice because “Yanibo has no shame”.

In the United Kingdom, when a Politician commits any act of shame like adultery, stealing, taking bribe, on or before he/she is caught would resign in order not to perverse the cause of justice but killers, thieves, adulterers etc. are common among the Nigerian Politicians because they have no shame.  They use their position to perverse the cause of justice.

This Yoruba Folklore that depicted that “Shamelessness is the king of all Vices” is worthy of note for the people to be mindful of the kind of Politician by casting their votes to elect “Decent” Politicians to repair what the” Shameless” ones has destroyed.

Share Button

Originally posted 2014-05-13 10:15:03. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn àròsọ bi obinrin ti sọ Àmọ̀tékùn di alábàwọ́n: The Folklore on how a woman turned the Leopard to a spotted animal.

Ni igba kan ri, Àmọ̀tékùn ni àwọ̀ dúdú ti ó jọ̀lọ̀, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ kan, Àmọ̀tékùn wá oúnjẹ õjọ́ rẹ lọ.  Ó dé ahéré kan, ó ṣe akiyesi pe obinrin kan ńwẹ̀, inú rẹ dùn púpọ̀ pé òhún ti ri oúnje.  O lúgọ de asiko ti yi o ri àyè pa obinrin yi fún oúnjẹ.

Yorùbá ni “Ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ ẹni la fi npa ejò”.  Nigbati obinrin yi ri Àmọ̀tékùn, pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ó fi igbe ta, ó ju kàrìnkàn ti ó fi ńwẹ̀ pẹ̀lú ọṣẹ híhó inú rẹ lù.  Àmọ̀tékùn fi eré si ṣùgbọ́n, gbogbo ọṣẹ ti ó wà ninu kànrìnkàn ti ta àbàwọ́n si ara rẹ lati ori dé ẹsẹ̀ rẹ, eleyi ló sọ Àmọ̀tékùn di alámì tó-tò-tó lára titi di ọjọ́ oni.  (Ẹ ka itàn àròsọ yi ninu iwé ti M.I. Ogumefu kọ ni èdè Gẹ̀ẹ́si).

Yorùbá ma nlo àwọn àròsọ itàn wọnyi lati kọ́ àwọn ọmọdé ni ẹ̀kọ́.  Yorùbá ni “Ẹni ti ó bá dákẹ́, ti ara rẹ á ba dákẹ́”, nitori eyi ẹ̀kọ́ pàtàki ti a ri ninu itàn àròsọ yi ni pé, kò yẹ ki enia fi ìbẹ̀rù dúró lai ṣe nkankan ti ewu bá dojú kọni ṣùgbọ́n ki á lo ohun kóhun ti ó bá wà ni àrọ́wótó lati fi gbèjà ara ẹni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-31 18:08:54. Republished by Blog Post Promoter