Category Archives: Yoruba Community

“Tori wèrè ìta la ṣe n ni wèrè inú ile”: Idibò lati yan Olóri Òṣèlú ni ọdún Egbãlemẹdógún – Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu Fakọyọ – “It takes a mad family member to confront an external aggression/madness”: Election 2015 Senator Bola Ahmed Tinubu was gallant

Ẹ̀rù ba onilé àti àlejò fún Nigeria nitori idibò à ti yan Olóri Òṣèlú à̀ti àwọn Òṣèlú yoku, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun pe ọjọ́ na ti wá, ó ti lọ, ilú ti yan Olóri Òṣèlú tuntun Ọ̀gágun Muhammadu Buhari lati gba ipò lọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Goodluck Ebele Jonathan.

Ẹgbẹ́ Òṣèlú Alágboorun ti ó ti ṣe Ìjọba fún ọdún mẹrindinlógún, ti ṣe iléri wi pé àwọn yio wa lori oyè fún àádọ́ta ọdún nitori ẹgbẹ́ wọn ló pọ̀jù ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú.  Yorùbá pa òwe pé “À ti gba ọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́, ki ṣe ojú bọ̀rọ̀” pàtàki, à ti gba ipò lọ́wọ́ Òṣèlú ki ṣe ojú bọ̀rọ̀.  Gẹ́gẹ́ bi òwe yi, ẹnikẹni mọ̀ pé Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ki fẹ gbé ipò silẹ̀.  Bi ó bá ṣe é ṣe wọn ò kọ lati kú si ipò, nitori wọn kò sin ará ilú.

Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu ṣe àtilẹhin rẹ fún Ọ̀gágun Muhammadu Buhari  -  APC Rally

Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu ṣe àtilẹhin rẹ fún Ọ̀gágun Muhammadu Buhari – APC Rally

Yorùbá sọ wi pé “Àgbájọ ọwọ́ la fi nsọ̀yà”, lai si ipa ti Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu kó lati kó ẹgbẹ yoku mọ́ra àti àtilẹhin rẹ fún Ọ̀gágun Muhammadu Buhari lati  jade ni igbà kẹrin fun ipò Olóri Oselu, “Àyipadà” ti ará ilú fẹ́ kò bá ma ṣe e ṣe.

 

ENGLISH TRANSLATION  
Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-04-03 21:08:29. Republished by Blog Post Promoter

ÀWÒRÁN ÈLÒ ỌBẸ̀ YORÙBÁ – PHOTO GALLERY OF SOME YORUBA SOUP/STEW/SAUCE INGREDIENTS

Share Button

Originally posted 2013-05-03 23:19:39. Republished by Blog Post Promoter

“Èkó – Aginjù laarin àwọn Olú Ilú Àgbáyé”: “Lagos – A Jungle among the World Big Cities”

Èkó ni olú ilú Nigeria fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ki àwọn Ijọba Ológun tó kó Olú Ilú Nigeria lọ si Abuja ni bi ọdún mẹrinlélógún sẹhin.  Ki kó olú ilú kúrò ni Èkó kò din èrò ti o nwọ Èkó kù, ilú Èkó ngbòrò si ni, ṣùgbọn bi èrò ti npọ si, Ijọba àpapọ̀ kò ran Eko lọwọ nipa ipèsè owó tó tó ni àsikò fún ohun amáyédẹrùn.

Sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀ - Heavy Lagos traffic. Courtesy: @theyorubablog

Sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀ – Heavy Lagos traffic. Courtesy: @theyorubablog

Ká fi Èkó wé àwọn olú ilú yoku ni àgbáyé àti àwọn ilú nla ti omi yi ká, inira Èkó pọ̀ ju àwọn ilú wọnyi lọ.  Kò si iná mọ̀nàmọ́ná ti ó ṣe deede, kò si omi mimu fún ará ilú pàtàki fún àwọn agbègbè titun.  Eyi ti ó burú jù ni ki èniyàn jade, kó má mọ igbà ti ó ma padà wọlé nipa li lo bi wákàti mẹ́fà tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ ninú sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀, nitori ọ̀nà kò tó, bẹni kò dára, iwà-kuwà pọ̀ fún awakọ̀, ọkọ̀ àti èrò pọ̀ ju òpópó ọ̀nà lọ.

Bi Ijọba àpapọ̀ Nigeria ti ri owó ori gbà ni Èkó ju gbogbo àwọn ilú yoku lọ tó, kò si irànlọ́wọ́ lati tú ọ̀nà Ijọba àpapọ̀ ṣe.  Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, Ijọba Ológun di Èkó lọ́wọ́ lati pèsè ọkọ̀ ojú irin ti ó ngbé èrò púpọ̀ ti Gómìnà Lateef Jakande bẹ̀rẹ̀.  Bi Èkó ti tóbi tó, ibùdókọ òfúrufú kan ló wà lójú kan naa ni Ìkẹjà fún àwọn ti ó nlọ si gbogbo àgbáyé àti àwọn ti ó fẹ́ lọ si ilú Nigeria miran.  Lati igbà ti Ijọba Ológun ti lé àwọn àjòjì ti ó dá ilé ọjà nla silẹ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn Olówó ilú kò ronú lati ṣe irú ilé ọjà bẹ́ ẹ̀ si gbogbo agbègbè Èkó fún irọ̀rùn ará ilú ju bi gbogbo ọjà nla ti kó ori jọ si Erékùṣù Èkó.  Àwọn nkan wọnyi àti iwà ibàjẹ́ àti ojúkòkòrò Ijọba Ológun àti Alágbádá (Òṣèlú) ló sọ Èkó di aginjù laarin àwọn olú ilú àgbáyé.

A lérò wi pé Ijọba Òṣèlú ti àwọn ará ilú yàn fún “àyipadà” kúrò ninú iwà ibàjẹ́ tó gba orilẹ̀ èdè kan fún igbà pi pẹ́, yio wa àtúnṣe fún Èkó.  Gómìnà Akinwunmi Àmbọ̀dé ni lati wá àtúnṣe si iyà ti ojú ará ilú nri nipa gbi gbé ọkàn lé ọkọ̀ ilẹ́ fún ohun irinna nikan, nipa pi pari iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin àti ibùdókọ̀ ojú omi ti Ijọba Gómìnà Babátúndé Raji Fáṣọlá bẹ̀rẹ̀, ki wọn si ṣe kun nipa ipèsè ibùdókọ òfúrufú àti ohun amáyédẹrùn yoku.

“Èkó kò ni bàjẹ́ o – ó bàjẹ́ ti”.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-15 20:33:21. Republished by Blog Post Promoter

“A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ” – Ìdàpọ̀ Àríwá àti Gũsu Nigeria: – 1914 Amalgamation of the Northern and Southern Nigeria

Ó pé ọgọrun ọdún ni ọjọ́ kini, oṣù kini ọdún Ẹgba-̃le-mẹrinla ti Ìjọba Ìlú-Ọba ti fi aṣẹ̀ da Àríwá àti Gũsu orílẹ̀ èdè ti a mọ̀ si Nigeria pọ.  Ìjọba Ìlú-Ọba kò bere lọwọ ará ilú ki wọn tó ṣe ìdàpọ̀ yi, wọn ṣe fún irọ̀rùn ọrọ̀ ajé ilú ti wọn ni.

Yorùbá ni “À jọ jẹ kò dùn bi ẹni kan kò ri”.  Ni tõtọ, Ijọba Ilu-Ọba ti fún orilẹ̀ èdè Nigeria ni ominira, ṣùgbọ́n èrè idàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ kò tán.  Gẹgẹbi Olóyè Ọbafẹmi Awolọwọ ti sọ nigbati wọn ńṣe àdéhùn fún ominira pe: “ominira ki ṣe ni ti orúkọ ilú lásán, ṣùgbọ́n ominira fún ará ilú.  A ṣe akiyesi pe lẹhin ìdàpọ̀ ọgọrun ọdún, orilẹ̀ èdè ko ṣe ikan.

Yorùbá ni “A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ” Gẹgẹbi òwe yi, ki ṣe ki kó ọ̀kẹ́ aimoye owó lati ṣe àjọyọ̀ ìdàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ ló ṣe pàtàki, bi kò ṣé pé ki a tó ọ̀rọ̀ bára sọ.

Yorùbá ni “Ọ̀rọ̀ la fi dá ilé ayé”.  Bi ọkọ àti iyàwó bá wà lai bára sọ̀rọ̀, igbéyàwó á túká, nitori eyi, ó ṣe pàtàki ki gbogbo ara ilú Nigeria lápapọ̀ ṣe àpérò bi wọn ti lè bára gbé ki ilú má bã túká.

ENGLISH TRANSLATION

“One does not qualify to live with a person without also qualifying to talk to the person” – Amalgamation of the Northern and Southern Nigeria Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-07 23:11:15. Republished by Blog Post Promoter

Àjọ jẹ kò dùn bi Ẹni kan kò ri: Ìná dànù àwọn ọmọ Olówó Nigeria ni Ìlú-Ọba – Eating together is not fun when some are deprived: Squandering of Nigeria Wealth in the UK, TV Channel 4 Documentary

Lati ọjọ́ ti aláyé ti dá ayé ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ti wà.  Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kún fún ọrọ̀ oriṣiriṣi, ṣùgbọ́n, iwà àpà, ojúkòkòrò, ki kó ti ilé dà si ita, àti ìfẹ́ àjòjì ju ara ilé ẹni lọ, ló fa iṣẹ́ ti ó pọ̀ ni Ilẹ̀-Aláwọ̀dúdú.  Iwà burúkú wọnyi, pàtàki laarin àwọn Olóri ilú tàbi alágbára ló fa ti ta ara ẹni lẹ́rú si Òkè-Òkun, ogun abẹ́lé àti òwò ẹrú ti ayé òde òni ṣi wà.  Àwọn Òṣèlú àti Olóri ilú kò ti kọ́ ọgbọ́n, nitori wọn nṣe àṣiṣe si nipa li lo iṣẹ ti wọn gbà lai ṣe kó owó ilú jẹ, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́ ló fa ibàjẹ́ ohun amáyédẹrùn àti ìṣẹ́ laarin ọrọ̀ ni orilẹ̀ èdè Nigeria.

Melo ninú ọmọ ayé òde òni ló ránti àwọn Ọlọ́rọ̀ ilẹ̀ Yorùbá ni aadọta ọdún sẹhin?  Òmíràn kò mọ itumọ̀ ọ̀rọ̀ Èkó/Yorùbá pé “Bi ó ti ẹ lówó bi Da Rocha” lai bèrè pé tani Da Rocha?  Àwọn Ọlọ́rọ̀ àná bi Candido Joao Da Rocha, Ọlọ́rọ̀ owó ọ̀kẹ́ aimoye àkọ́kọ́ ni orilẹ̀ èdè Nigeria ti ilú Èkó, Olóyè Adéọlá Odùtọ́lá ọ̀gá Oníṣòwò ti Ìjẹ̀bú-Òde ti ìpínlẹ̀ Ògùn, Oloye Àjàó, S. Bọlaji Bakare, I.O. Àjànàkú Iléṣà, Olóyè T.A. Oni & ati àwọn ọmọ-kunrin rẹ ni Ìbàdàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Oṣinọwọ oníṣòwò ọkọ̀ irinna ni Èkó, Mobọ́láji Bank-Anthony, Asábọ́rọ̀, ọmọ Ìkárọ̀ ni ẹ̀gbẹ́ Ọ̀wọ̀ ni ìpínlẹ̀ Ondo àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ ti wọn ti gbàgbé wọn pẹ̀lú ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀.  Àwọn ti wọn ránti, ki ṣe nitori ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀ láyé ni èrò ránti ṣùgbọ́n àwọn ọmọ tó gba ẹ̀kọ́ ni ó lè jẹ ki wọn ṣe iránti wọn àti bi wọn ti lo ọrọ̀ na a fún lati ṣe oore fún àwọn aláìní.

Àwọn Ọlọ́rọ̀ Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kò kọ́ ọgbọ́n ninú itàn igbẹhin Ọba àti Ìjòyè ti kò lo ipò wọn dáradára, àwọn ti ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ, tàbi ti ó lo ipò wọn lati fi tẹ ará ilú mọ́lẹ̀ ni àtijọ́.  Irú ọrọ̀ bẹ́ ẹ̀  kò bá wọn kalẹ́ bẹni ìrántí wọn kò dára.

Ni ọjọ́ keji ọ̀sẹ̀, ọjọ́ keje oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbàá-lémẹ́rìndínlógún, ilé-iṣẹ́ Amóhùn-máwòrán Kẹrin ni Ilú-Ọba fi àpẹrẹ hàn bi àwọn ọmọ Ọlọ́rọ̀ lati Nigeria ti mba owó ninú jẹ́ ni Ilú-Ọba.  Yorùbá ni “Ohun ti a kò bá jiyà fún, ki i lè tọ́jọ́”.  Wọn nná owó ti ọgọrun enia lè ná ni ọdún kan ni alẹ́ ọjọ́ kan lai ronú ọ̀pọ̀ aláìní ni orílẹ̀ èdè wọn, ti Bàbá wọn ti fa ijiyà fún lati kó ọrọ̀ ti wọn nná dànù jọ.  Kò si ìyàlẹ́nu ni irú iwà ti àwọn ọmọ ọlọ́rọ̀ Nigeria wọnyi hù nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn bàjẹ́, wọn kò ni ẹ̀kọ́, wọn kò mọ iyi owó nitori wọn kò ṣiṣẹ́ fun.

ENGLISH TRANSLATION  Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-06-21 23:57:06. Republished by Blog Post Promoter

A bèrè fún àròkọ ni Èdè àti Àṣa Yorùbá fún Idije Àkọ́kọ́ – The Yoruba Blog is inviting articles on Yoruba Language and Culture for the 2015 Annual Yoruba Blog Competition

A rọ ẹnikẹni ti ó ni ìfẹ́ èdè àti àṣà Yorùbá (pàtàki ọmọ ilé-iwé giga ti ó nkọ ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá) ki ó kọ àròkọ fún “theyorubablog” lóri ayélujára.  Àròkọ ti èrò bá kà jù tàbi ti wọn ni ìfẹ́ rẹ jù yio gba ẹ̀bùn ti a o ṣe ni ọdọọdún.  Àròkọ na a gbọ́dọ̀ ni àwọn ohun wọnyi: Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-03 09:30:41. Republished by Blog Post Promoter

Olóri Òṣèlú Nigeria Muhammadu Buhari àti Àtẹ̀lé rẹ Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Oṣinbajo pé Ọgọrun Ọj̀ọ́ lori oye – 100 Days of Buhari/Osinbajo in Office

 

Ọmọ tó rù njẹun diẹ diẹ - A Malnourished baby being fed little by little.  Courtesy: @theyorubablog

Ọmọ tó rù njẹun diẹ diẹ – A Malnourished baby being fed little by little. Courtesy: @theyorubablog

Share Button

Originally posted 2015-09-08 23:59:31. Republished by Blog Post Promoter

“A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù”: Ìmọ̀ràn fún Òṣèlú tuntun àti àwọn ará ilú Nigeria – It takes more than One Day to Nourish a Malnourished child”: Advice for the Newly Elected Politicians and the Nigerian People

Ọmọ ki dédé rù lai ni idi.  Lára àwọn idi ti ọmọ lè fi rù ni: àìsàn, ebi, òùngbẹ, ìṣẹ́, ai ni alabojuto, òbí olójú kòkòrò, ai ni òbí àti bẹ ẹ bẹ lọ.

Orilẹ̀ èdè Nigeria ti jẹ gbogbo ìyà àwọn ohun ti ó lè mú ki ọmọ rù yi, lọ́wọ́ Ìjọba Ológun àti Òsèlú fún ọ̀pọ̀ ọdún.  Nigbati àwọn òbí ti ó fẹ́ràn ọmọ bi Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti àwọn àgbà ti ó bèrè fún Ominira lọwọ Ilú-Ọba, ṣe Òsèlú, ilú kò rù, pàtàki ọmọ Yorùbá.  Wọn fi ọrọ̀ ajé àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ipinlẹ̀, pèsè ohun amáyédẹrùn fún ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, àwọn tó jade ni ilé-iwé giga ri iṣẹ́ gidi àti pé àwọn ará ilú tẹ̀ lé òfin.  Eyi mú ìlọsíwájú bá ilẹ̀ Yorùbá ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.

Ilú bẹ̀rẹ̀ si rù lati igbà ti Ìjọba Ológun àkọ́kọ́ ti fi ipá kó gbogbo ipinlẹ̀ Nigeria si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ni  ọdún mọ́kàndinlãdọta sẹhin .  Lati igbà ti wọn ti kó ọrọ̀ ajé gbogbo ipinlẹ̀ si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti a lè pè ni “Òbí” ti jinà si ará ilú ti a lè pè ni “Ọmọ” ti rù.  Ojúkòkòrò àti olè ji jà Ìjọba Ológun àti Òṣèlú lábẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti fa ebi, òùngbẹ àti àìsàn fún ará ilú.

Ni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sẹhin, Olóri Òsèlu tuntun Muhammadu Buhari àti àtẹ̀lé rẹ Túndé Ìdíàgbọn ṣe Ìjọba fún ogún oṣù gẹgẹ bi Ìjọba Ológun.  Nigbati wọn gba Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Òṣèlú ti ó ba ilú jẹ́ pẹ̀lú iwà ìbàjẹ́ ti wọn fi kó ilú si igbèsè lábẹ́ Olóri Òṣèlú Shehu Shagari, wọn fi ìkánjú ṣe idájọ́ fún àwọn tó hu iwà ibàjẹ́, eleyi jẹ ki ilú ké pé Ìjọba wọn ti le jù.  Ká ni ilú farabalẹ̀ ni àsikò na a, ilú ki bá ti dára si.  Nigbati Olóri-ogun Badamasi Babangida gba Ìjọba, inú ilú dùn nitori àyè gba ará ilú lati ṣe bi wọn ti fẹ lati ri owó.  Eleyi jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ olówó ojiji pọ̀ si lati igbà na a titi di oni.  Àyè àti ni owó ojiji nipa ifi owó epo-rọ̀bì ṣòfò, ki kó owó ìpèsè ohun amáyédẹrùn jẹ, gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti iwà ìbàjẹ́, ló pa ilé-iwé giga, ilé-ìwòsàn, pàtàki ìpèsè iná-mọ̀nàmọ́ná, ìdájọ́ àti bẹ ẹ bẹ lọ.

A lè lo òwe “A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù” ṣe àlàyé pé iwà ìbàjẹ́ àti ohun tò bàjẹ́ fún ọdún pi pẹ́ kò ṣe tún ṣe ni ọjọ́ kan, nitori eyi, ki ará ilú ṣe sùúrù fún Ìjọba tuntun lati ṣe àtúnṣe lati ìbẹ̀rẹ̀.  Ki Ìjọba tuntun na a mọ̀ pé “Ori bi bẹ́, kọ́ ni oògùn ori fi fọ́”, nitori eyi ki wọn tẹ̀ lé òfin lati ṣe ìdájọ́ fún àwọn ti ó ba ilú jẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-01-12 10:09:45. Republished by Blog Post Promoter

Ayẹyẹ Ọjọ́-ibi Aadọrun Ọdún, Ọbabinrin Elizabeth Keji – Celebration of 90th Birthday of Queen Elizabeth II

Ọbabinrin Elizabeth Keji ni ibi Ayẹyẹ Ọjọ́-ibi Aadọrun Ọdún – Queen Elizabeth II at her 90th Birthday celebration.

Ọbabinrin Elizabeth Keji ni ibi Ayẹyẹ Ọjọ́-ibi Aadọrun Ọdún – Queen Elizabeth II at her 90th Birthday celebration.

Ọbabinrin Elizabeth Keji, pé aadọrun ọdún láyé ni ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálémẹrindinlólgún.  Gbogbo ará ilú àti àwọn Ìjọ Onigbàgbọ́ pé jọ lati ṣe ayẹyẹ à ṣe pọ̀ fún Ọbabinrin ni ọjọ́ Ìsimi, ọjọ́ kejila, oṣù kẹfà ọdún.  Eleyi bọ si àsikò ti ọkọ rẹ Philips pé ọgọrundinmarun ọdún.

Lẹhin ti Ọbabinrin Elizabeth keji gun ori oyè ni ọdún mẹtalelọgọta sẹhin, ó bẹ ilú Èkó wò ni ọgọta ọdún sẹhin, nigbati Ilú Èkó jẹ́ Olú-Ilú orilẹ̀ èdè Nigeria ki a tó gba Òminira lábẹ́ Ilú-Ọba ni odun Ẹdẹgbaalelọgọta.  A ṣe yi ṣe àmọ́dún o.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán wọnyi.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-06-14 22:22:27. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ bá wa gbé ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò. Àwọn Ilé Ìdájọ́ Àgbà ni ìlú Amerika ṣe ìdájọ wípé “ìgbéyàwó ko di dandan kó jẹ́ laarin ọkùnrin àti obinrin” : US Supreme Court Decides Marriage Does not Have to be Man & Woman

Two men rejoicing

A gay couple rejoicing over the repeal of the Defense of Marriage Act — June 26, 2013. Image is from AP/BBC

Ẹ bá wa gbé ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò. Àwọn Ilé Ìdájọ́ Àgbà ni ìlú Amerika ṣe ìdájọ wípé “ìgbéyàwó ko di dandan kó jẹ́ laarin ọkùnrin àti obinrin”. Bi wọn ti s’alaiye oro na si, wọn ni kò dára ki àwọn Aṣòfin ti a mọ si “Congress”, sọ wípé “ìgbéyàwó lati jẹ́ laarin ọkùnrin àti obìnrin ni kan ṣoṣo”. Àkíyèsí ti wọn ṣe ni wípé, ìdí ti àwọn Aṣòfin ṣe sọ bẹ̃, ni pé wọn o fẹ́ràn àwọn ti o nṣe igbeyawo ọkùnrin si ọkùnrin tabi obìnrin si obìnrin.

Ẹ jẹ́ ki a yẹ ọ̀rọ̀ yi wo bó yá a fẹ́ràn ẹ, tàbi a o fẹ́ràn ẹ, ṣe àṣà àdáyébá Yorùbá kankan wa, bi òwe tàbí nkan bẹ̃, ti ó sọ ìdí ti a ṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni ọpọlọpọ ẹ̀tọ́ ti a n fun wọn?

Ẹ jọ̀wọ́, ẹyin ará Yoruba blog, ẹ bá wa da si. Ẹ sọ ìdí ti aṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni oriṣiriṣi ẹ̀tọ́, ẹ̀bùn lọ́jọ́, ìgbéyàwó àti àyẹ́sí fún àwọn tó bá wà ni ilé ọkọ.

Ìdájọ́ yi ṣe pàtàkì, bi o ti ẹ jẹ wípé Amerika lo yi òfin padà pe ìgbéyàwó ki ṣe laarin ọkùnrin àti obìnrin mọ́ lọ́jọ́ òní, ni ọjọ́ kan, Yorùbá, orílẹ̀ èdè Nigeria àti gbogbo ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú yio ṣe ipinu ọ̀rọ̀ yi.

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-06-28 15:27:02. Republished by Blog Post Promoter