Originally posted 2015-07-07 19:41:40. Republished by Blog Post Promoter
“Ògòngò lọba ẹiyẹ” – “Ostrich is the King of Birds”
Ògòngò jẹ ẹiyẹ ti ó tóbi jù ninú gbogbo ẹiyẹ, ẹyin rẹ ló tún tóbi jù. Ọrùn àti ẹsẹ̀ rẹ ti ó gún jẹ́ ki ó ga ju gbogbo ẹiyẹ yoku. Ògòngò ló lè sáré ju gbogbo eiye lọ lóri ilẹ̀. Eyi ló jẹ́ ki Yorùbá pe Ògòngò ni Ọba Ẹiyẹ. Ọpọlọpọ ẹiyẹ bi Ògòngò kò wọ́pọ̀ mọ́ nitori bi ilú ti nfẹ si bẹni àwọn eiye wọnyi nparẹ́, a fi bi èniyàn bá lọ si Ilé-ikẹransi lati ri wọn.
Àwọn onírúurú ẹiyẹ ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá, àwọn eyi ti ó wọ́pọ̀ ni ilú tàbi ilé (ẹiyẹ ọsin)ni, Adiẹ (Àkùkọ àti Àgbébọ̀ adiẹ), Pẹ́pẹ́yẹ, Ẹyẹlé, Awó, Ayékòótó/Odidẹrẹ́ àti Ọ̀kín. Àwọn ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ninú igbó ṣùgbọ́n ti ará ilú mọ̀ ni: Àṣá, Ìdì, Òwìwí, Igún/Àkàlàmàgbò àti Lekeleke. Àwọ̀ oriṣirisi ni ẹiyẹ ni, irú ẹiyẹ kan lè ni àwọ̀ dúdú bi aró, kó́ tun ni pupa tàbi funfun, ṣùgbọ́n orin Yorùbá ni ojú ewé yi fi àwọ̀ ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ẹiyẹ miran hàn. Fún àpẹrẹ, Lekeleke funfun bi ẹfun, Agbe dúdú bi aró, bẹni Àlùkò pọn bi osùn. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àti pipè orúkọ di ẹ ninú àwon ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ni ojú ewé yi.
Agbe ló laró ————— ki rá ùn aró
Àlùkò ló losùn ———— ki rá ùn osùn
Lekeleke ló lẹfun ——– ki rá ùn ẹfun
Ka má rá ùn owó, ka má rá ùn ọmọ
Ohun tá ó jẹ, tá ó mu, kò mà ni wọn wa ò.
ENGLISH TRANSLATION
Ostrich is the biggest and has the largest eggs among the birds. The long neck and legs made it taller than all the other birds. Ostrich is also the fastest runner on land more than all the birds. This is why Yoruba crowned Ostrich as the King of Birds. Many wild birds such as Ostrich are almost extinct as a result of the expansion of towns and cities displacing the wild birds which can now be seen at the Zoo.
There are various types of birds in Yoruba land, the most common at home or in town (domestic birds) are: Chicken (Cock and Hen), Duck, Pigeon, Guinea Fowl, Parrot, and Peacock. The common wild birds that are known in the town or communities are: Falcon/Kite, Eagle, Owl, Vulture and Cattle-egret. Birds are of various colours, one species of bird can come in various colours, while some are black like the dye, some are red like the camwood, and some are white, but the Yoruba song on this page depicted the common colours that are peculiar with some species of birds. For example, Cattle-Egret are white like chalk, Blue Turaco are coloured like the dye and Red Turaco are reddish like the camwood. Check out the pictures and prononciation of some of the birds that are common in Yoruba land on this page.
Originally posted 2014-10-17 12:27:16. Republished by Blog Post Promoter
Ohun jíjẹ pàtàki ti à ńfi Iṣu Ewùrà ṣe: Ìfọ́kọrẹ́ tàbi Ìkọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀.
Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ìfọ́kọrẹ́/Ìkọ́kọrẹ́ lójú iwé yi.
Gbé epo kaná
Kó èlò bi ẹ̀jà tútù tàbi gbigbẹ, edé, pọ̀nmọ́ sinú ikòkò epo-pupa yi
Fi iyọ̀ àti iyọ̀ igbàlódé àti omi si inú ikòkò yi lati se omi ọbẹ ìkọ́kọrẹ́
Fọ Iṣu Ewùrà kan
Bẹ Ewùrà yi
Rin iṣu yi (pẹ̀lú pãnu ti a dálu lati fi rin gãri, ilá tàbi ewùrà)
Fi iyọ̀ bi ṣibi kékeré kan po ewùrà ri-rin yi
Ti ó bá ki, fi omi diẹ si lati põ
Lẹhin pi pò, dá ewùrà pi pò yi sinú omi ọbẹ̀ ti a ti sè fún bi iṣẹ́jú mẹdogun
Rẹ iná rẹ silẹ̀, se fún bi ogún iṣẹ́jú
Ro pọ
Lẹhin eyi bu fún jijẹ.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-03-28 20:26:48. Republished by Blog Post Promoter
Ìtán ti a fẹ́ kà loni dá lóri Bàbá tó kó gbogbo Ẹrù fún Ẹrú – The story of the day is about a father who bequeathed all his inheritance to his Chief Slave
Originally posted 2017-12-06 00:23:08. Republished by Blog Post Promoter
Ni Iránti Bàbá Ẹgbẹ́ Òṣèré Nigeria: Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde – In Memory of “Father of Nigerian Theatre”: Late Chief Hubert Adedeji Ogunde
Ẹbi, ará, iránṣẹ́ Ìjọba àti àwọn ọmọ Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde pé jọ ni ọjọ́ kẹrinlélógún oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún, ni ilú Ìjẹ̀bú Ọ̀sọ̀sà ti ipinlẹ̀ Ògùn lati ṣe irànti. Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde jade láyé ni ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹrin ọdún mẹ̃dọgbọn sẹhin.
Eré ṣi ṣe bẹrẹ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin nigbati Yorùbá ba nṣe ọdún Eégún, eyi ti wọn fi nṣe iránti àwọn Bàbánlá Yorùbá. Ni àsikò ọdún eégún, orin, ilú àti ijó ni wọn fi nda ilú lára yá pàtàki ni iwájú ilé Ọba. Nigbati Yorùbá gba ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, dipò ọdún eégún, ọdún Ìgbàgbọ́ bi Ajinde àti Kérésìmesì ni ọmọ ilé-iwé ọjọ́ Ọ̀sè ma nṣe eré itàn Bibeli lati dá ijọ lára yá. Lára àwọn Òṣèré Yorùbá ti ó ti ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ jade ni Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde, Olóògbé Kọ́lá Ògúnmọ́lá àti Olóògbé Dúró Ládipọ̀.
Itàn gbi gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ pẹ̀lú eré, ilú àti orin kọjá ilẹ̀ Yorùbá titi dé Òkè-òkun kò pé lai sọ nipa Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde ti ó kọ́kọ́ dá “Ẹgbẹ́ Iṣẹ́ Òṣèré” silẹ̀ ni aadọrin ọdún sẹhin. Olóògbé Ogunde lo ẹ̀bùn ti ó ni fi gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ gidigidi.
Gẹ́gẹ́ bi ikan ninú orin àti eré ti Olóògbé Ogunde ṣe “Yorùbá Ronú”, bi Yorùb́a bá ronú, ki ṣe ẹbi nikan ló yẹ ki ó tọ́jú ohun ti Ologbe fi silẹ̀. Ó yẹ ki Ìjọba, pàtàki Ìjọba àwon ipinlẹ̀ Yorùbá para pọ̀ lati tọ́jú ogún “ilé iṣẹ́ Òṣèré ni Ọ̀sọ̀sà” fún li lò àwọn ọ̀dọ́ àti Òṣèré ni iránti Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2015-05-05 19:24:57. Republished by Blog Post Promoter
“Bi a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” – “If one lives long enough, one will consume as much meat as an elephant”
Erin jẹ ẹran ti ó tóbi ju gbogbo ẹranko ti a mọ̀ si ẹran inú igbó àti ẹran-àmúsìn, ti a mọ̀ ni ayé òde òni. Bi a bá ṣe àyẹ̀wò bi Yorùbá ti ńgé ẹran ọbẹ̀, ó ṣòro lati ro oye ẹran ti enia yio jẹ ki ó tó Erin.
Bawo ni òwe Yorùbá ti ó ni “Bi a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” ti wúlò fún ẹni ti ki jẹ ẹran ti a mọ̀ si “Ajẹ̀fọ́”? Àti Ajẹ̀fọ́ àti Ajẹran ni òwe yi ṣe gbà ni iyànjú pé “Ohun ti kò tó, ḿbọ̀ wá ṣẹ́ kù”. Fún àpẹrẹ, bi enia bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nibi kékeré, bi ó bá tẹramọ́, yi o di ọ̀gá, yio si lè ṣe ohun ti ẹgbẹ́ rẹ ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ibi giga ṣe. Bi enia bá ni oreọ̀fẹ́ lati pẹ́ láyé, ti ó dúró tàbi ni sùúrù, yio ri pé ohun jẹ ẹran ti ó tó Erin.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2015-05-12 18:29:05. Republished by Blog Post Promoter
Àgbo – Ewé àti Egbòigi fún ìtọ́jú – Yoruba Herbal remedies/Traditional medicine
Ki oògùn Òyinbó tó gbòde, ewé àti egbòigi ti ó wà ni oko tàbi àyíká ilé ni Yorùbá fi nki àgbo lati dí àisàn lọ́wọ́ tàbi wo àisàn. Àwọn gbajúmọ̀ àti ọ̀dọ́ ayé òde òni ti kọ àgbo ti wọ́n fi ewé àti egbòigi ṣe fún oògùn àti iṣe Òyinbó.
Fún àkọsílẹ̀, Olùkọ̀wé èdè Yorùbá lóri ayélujára yi, yio bẹ̀rẹ̀ si ṣe àkọsílẹ̀ ewé àti egbòigi ti wọn fi ńto àgbo àti èyi ti ó wà fún itọ́jú ara. A ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àgbo-ibà, nitori ibà ló wọ́pọ̀ jù ninú gbogbo oriṣiriṣi àrùn.
ENGLISH TRANSLATION
Most Yoruba elders above the age of fifty who grew up outside Lagos, were raised drinking herbal decoction or using herbs as preventive medicine or as curative. Up till today, some Yoruba herbal decoction are still very popular for the prevention or cure of pile or haemorrhoid known in Yoruba as “Jẹ̀dí/Jẹ̀díjẹ̀dí”.
Prior to Western medicine, Yoruba people relied on local herbs as preventive medicine and for curing the sick. There was a drift from exclusive reliant on herbal medicine for primary healthcare to Western medicine and lifestyle, hence the neglect of local herbs especially by the elites and the youths.
In order to preserve Yoruba traditional herbs, The Yoruba Blog and her team will begin to document online Yoruba local herbs and remedies. Publication will begin with Malaria which is the most common ailment.
Originally posted 2020-09-01 18:46:00. Republished by Blog Post Promoter
ABD YORÙBÁ – Yoruba Alphabet
“ABD”, ìbẹ̀rẹ̀ iwé kikà ni èdè Yorùbá – Yoruba Alphabets “ABD” is the beginning of Yoruba education.
Bi ọmọdé bá bẹrẹ ilé-iwé alakọbẹrẹ, èdè Yorùbá ni wọn fi nkọ ọmọ ni ilé-iwé lati iwé kini dé iwé kẹta. Ìbẹ̀rẹ̀ àti mọ̃ kọ, mọ̃ ka ni èdè Yorùbá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ki kọ àti pipe ABD. Ẹ ṣe àyẹ̀wò kikọ àti kikà ABD pẹ̀lú àwòrán ni ojú iwé yi.
ENGLISH TRANSLATION
When children are enrolled for primary education, they are taught in Yoruba language from Primary one to three. Learning how to write or read Yoruba language begins with writing and pronouncing ABD (Yoruba Alphabets). Check out writing and pronouncing Yoruba Alphabets – ABD with picture illustration on this page.
Learn the Yoruba alphabets with illustrations and pronunciation.
Originally posted 2014-05-01 16:30:38. Republished by Blog Post Promoter
“Ori ló mọ iṣẹ́ àṣe là”: Ògbójú-ọdẹ di Adẹmu fún Ará-Ọ̀run – “Destiny determines the work that leads to prosperity”: Great Hunter became Palm-wine tapper for the Spirits
Ọkunrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe. Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni. Nigbati kò ri ẹran pa mọ́, ó di o Ọdẹ-apẹyẹ.
Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ. Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa. Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú. Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi ó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará-Ọ̀run – àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá. Inu bi àwọn Ará-Ọ̀run nitori Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn. Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn, ki àwọn tó pá. Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nipa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọde. Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ. Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nitori naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn.
Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin. Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa. Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun. Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin lati jẹ ki àwọn Ará-Ọ̀run mọ̀ pé ohun ti dé, lẹhin èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará-Ọ̀run. Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá. Ògbójú-ọdẹ á má kọrin bayi:
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ki lo wá ṣe n’ilẹ̀ yi o
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ẹmu ni mo wá dá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Èlèló lẹmu rẹ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ọ̀kànkàn ẹgbẹ̀wá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Gbẹ́mu silẹ ko maa lọ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbàaa
Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi. Yorùbá ni “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú”. Àjàpá, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí-kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nitori àti mọ idi ọrọ̀ rẹ. Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ, eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará-Ọ̀run dúró. Gẹgẹbi ọ̀rẹ́, ó bẹ Àjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará-Ọ̀run. Ó ṣe ikilọ fún Àjàpá, bi ikilọ ti àwọn Ará-Ọ̀run fi silẹ̀. Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará-Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ. Àjàpá, fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará-Ọ̀run ti ńmu ẹmu. Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu. Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará-Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́. Nigbati wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Àjàpá, sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa. Continue reading
Originally posted 2014-07-18 20:50:09. Republished by Blog Post Promoter
Bi Irọ́ bá lọ fún Ogún Ọdún, Òtítọ á ba Lọ́jọ́ Kan – Ìbò Ọjọ́ Kejilá Oṣù Kẹfà Ọdún fún MKO Abiọ́lá Kò Gbé – Truth will always catch up lies – June 12 Election of Late Chief MKO Abiola is not in Vain
Lẹhin ọdún mẹẹdọgbọn ti Ijoba Ologun Ibrahim Babangida fagilé ìbò ti gbogbo ilú dì lai si ìjà tàbi asọ̀ tó gbé Olóògbé Olóyè Moshood Káṣìmáawòó Ọláwálé Abíọ́lá wọlé, Ìjọba Muhammadu Buhari sọ ọjọ́ kejilá oṣù kẹfà di “Ọjọ́ Ìsimi Ìjọba Alágbádá” fún gbogbo orílẹ̀-èdè Nigeria.
Ìjọba Ológun àti Ìjọba Alágbádá ti o ti ṣèlú́ lati ọdún mẹẹdọgbọn sẹhin rò wi pé ó ti pari, nitori wọn fẹ́ ki ọjọ́ yi di ohun ìgbàgbé, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Bi irọ́ bá lọ fún ogún ọdún, òtítọ́ á ba lọ́jọ́ kan”. Òtítọ́ ti bá irọ́ ọdún mẹẹdọgbọn ni ọjọ́ òní ọjọ́ kejila oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún. Olórí Òṣèlú Muhammadu Buhari dójú ti àwọn onírọ́ ti ó gbá gbogbo ẹni ti ó dìbò lójú.
Ki Ọlọrun kó dẹlẹ̀ fún Olóògbé Olóyè MKO Abíọ́lá, gbogbo àwọn ti ó kú lai ri àjọyọ̀ ọjọ́ òní.
ENGLISH TRANSLATION
Twenty-five years after a peaceful and fair election of late Chief MKO Abiola was annulled by the military Junta Ibrahim Babangida, the government of President Muhammadu Buhari declared “June 12 Democracy Day and National Public Holiday”. Continue reading
Originally posted 2018-06-13 02:32:27. Republished by Blog Post Promoter